25 O si wi fun wọn pe, Ẹnyin ti oyé ko yé, ti o si yigbì li àiya lati gbà gbogbo eyi ti awọn woli ti wi gbọ́:
26 Ko ha yẹ ki Kristi ki o jìya nkan wọnyi ki o si wọ̀ inu ogo rẹ̀ lọ?
27 O si bẹ̀rẹ lati Mose ati gbogbo awọn woli wá, o si tumọ̀ nkan fun wọn ninu iwe-mimọ gbogbo nipa ti ara rẹ̀.
28 Nwọn si sunmọ iletò ti nwọn nlọ: o si ṣe bi ẹnipe yio lọ si iwaju.
29 Nwọn si rọ̀ ọ, wipe, Ba wa duro: nitori o di ọjọ alẹ, ọjọ si kọja tan. O si wọle lọ, o ba wọn duro.
30 O si ṣe, bi o ti ba wọn joko tì onjẹ, o mu àkara, o sure si i, o si bù u, o si fifun wọn.
31 Oju wọn si là, nwọn si mọ̀ ọ; o si nù mọ wọn li oju.