37 Ṣugbọn àiya fò wọn, nwọn si dijì, nwọn ṣebi awọn rí iwin.
38 O si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ara nyin kò lelẹ̀? ẽsitiṣe ti ìrokuro fi nsọ ninu ọkàn nyin?
39 Ẹ wò ọwọ́ mi ati ẹsẹ mi, pe emi tikarami ni: ẹ dì mi mu ki ẹ wò o; nitoriti iwin kò li ẹran on egungun lara, bi ẹnyin ti ri ti mo ni.
40 Nigbati o si wi bẹ̃ tán, o fi ọwọ́ on ẹsẹ rẹ̀ hàn wọn.
41 Nigbati nwọn kò si tí igbagbọ́ fun ayọ̀, ati fun iyanu, o wi fun wọn pe, Ẹnyin ni ohunkohun jijẹ nihinyi?
42 Nwọn si fun u li ẹja bibu, ati afára oyin diẹ.
43 O si gba a, o jẹ ẹ loju wọn.