9 Ati nisisiyi pẹlu, a fi ãke le gbòngbo igi na: gbogbo igi ti kò ba so eso rere, a ke e lulẹ, a si wọ́ ọ jù sinu iná.
10 Awọn enia si mbi i pe, Kini ki awa ki o ha ṣe?
11 O dahùn o si wi fun wọn pe, Ẹniti o ba li ẹ̀wu meji, ki o fi ọkan fun ẹniti kò ni; ẹniti o ba si li onjẹ, ki o ṣe bẹ̃ pẹlu.
12 Awọn agbowode si tọ̀ ọ wá lati baptisi lọdọ rẹ̀, nwọn si bi i pe, Olukọni, kili awa o ha ṣe?
13 O si wi fun wọn pe, Ẹ máṣe fi agbara gbà jù bi a ti rán nyin lọ mọ́.
14 Awọn ọmọ-ogun si bère lọdọ rẹ̀, pe, Ati awa, kili awa o ṣe? O si wi fun wọn pe, Ẹ máṣe huwa ipá si ẹnikẹni, ki ẹ má si ṣe rẹ ẹnikẹni jẹ; ki owo onjẹ nyin to nyin.
15 Bi awọn enia si ti nreti, ti gbogbo wọn si nrò ninu ara wọn nitori Johanu, bi on ni Kristi bi on kọ́;