33 Ọkunrin kan si wà ninu sinagogu, ẹniti o li ẹmi aimọ́, o kigbe li ohùn rara,
34 O ni, Jọwọ wa jẹ; kini ṣe tawa tirẹ, Jesu ara Nasareti? iwọ wá lati pa wa run? emi mọ̀ ẹniti iwọ iṣe; Ẹni Mimọ́ Ọlọrun.
35 Jesu si ba a wi, o ni, Pa ẹnu rẹ mọ́, ki o si jade lara rẹ̀. Nigbati ẹmí eṣu na si gbé e ṣanlẹ li awujọ, o jade kuro lara rẹ̀, kò si pa a lara.
36 Hà si ṣe gbogbo wọn nwọn si mba ara wọn sọ, wipe, Ọ̀rọ kili eyi! nitori pẹlu aṣẹ ati agbara li o fi ba awọn ẹmi aimọ́ wi, nwọn si jade kuro.
37 Okikí rẹ̀ si kàn nibi gbogbo li àgbegbe ilẹ na yiká.
38 Nigbati o si dide kuro ninu sinagogu, o si wọ̀ ile Simoni lọ; ibà si ti dá iya aya Simoni bulẹ; nwọn si bẹ̀ ẹ nitori rẹ̀.
39 O si duro tirisi i, o ba ibà na wi; ibà si jọwọ rẹ̀ lọwọ: o si dide lọgan, o nṣe iranṣẹ fun wọn.