29 Ẹniti o ba si lù ọ ni ẹrẹkẹ kan, pa ekeji dà si i pẹlu; ati ẹniti o gbà agbada rẹ, máṣe da a duro lati gbà àwọtẹlẹ rẹ pẹlu.
30 Si fifun gbogbo ẹniti o tọrọ lọdọ rẹ; lọdọ ẹniti o si kó ọ li ẹrù, má si ṣe pada bère.
31 Gẹgẹ bi ẹnyin si ti fẹ ki enia ki o ṣe si nyin, ki ẹnyin ki o si ṣe bẹ̃ si wọn pẹlu.
32 Njẹ bi ẹnyin ba fẹ awọn ti o fẹ nyin, ọpẹ́ kili ẹnyin ni? awọn ẹlẹṣẹ pẹlu nfẹ́ awọn ti o fẹ wọn.
33 Bi ẹnyin si ṣore fun awọn ti o ṣore fun nyin, ọpẹ́ kili ẹnyin ni? awọn ẹlẹṣẹ pẹlu nṣe bẹ̃ gẹgẹ.
34 Bi ẹnyin si win wọn ni nkan lọwọ ẹniti ẹnyin ó reti ati ri gbà pada, ọpẹ́ kili ẹnyin ni? awọn ẹlẹṣẹ pẹlu nwin ẹlẹṣẹ, ki nwọn ki o le gbà iwọn bẹ̃ pada.
35 Ṣugbọn ki ẹnyin ki o fẹ awọn ọtá nyin, ki ẹnyin ki o si ṣore, ki ẹnyin ki o si winni, ki ẹnyin ki o máṣe reti ati ri nkan gbà pada; ère nyin yio si pọ̀, awọn ọmọ Ọgá-ogo li a o si ma pè nyin: nitoriti o ṣeun fun alaimore ati fun ẹni-buburu.