8 Omiran si bọ́ si ilẹ rere, o si rú soke, o si so eso ọrọrun. Nigbati o si wi nkan wọnyi tan, o nahùn wipe, Ẹniti o ba li etí lati fi gbọ́, ki o gbọ́.
9 Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si bi i lẽre, wipe, Kili a le mọ̀ owe yi si?
10 O si wi fun wọn pe, Ẹnyin li a fifun lati mọ̀ ọ̀rọ ijinlẹ ijọba Ọlọrun: ṣugbọn fun awọn miran li owe; pe ni riri, ki nwọn ki o má le ri, ati ni gbigbọ ki o má le yé wọn.
11 Njẹ owe na li eyi: Irugbin li ọ̀rọ Ọlọrun.
12 Awọn ti ẹba ọ̀na li awọn ti o gbọ́; nigbana li Èṣu wá o si mu ọ̀rọ na kuro li ọkàn wọn, ki nwọn ki o má ba gbagbọ́, ki a ma ṣe gbà wọn là.
13 Awọn ti ori apata li awọn, nigbati nwọn gbọ́, nwọn fi ayọ̀ gbà ọ̀rọ na; awọn wọnyi kò si ni gbòngbo, nwọn a gbagbọ fun sã diẹ; nigba idanwò, nwọn a pada sẹhin.
14 Awọn ti o bọ sinu ẹgún li awọn, nigbati nwọn gbọ́ tan, nwọn lọ, nwọn a si fi itọju ati ọrọ̀ ati irọra aiye fun u pa, nwọn kò si le so eso asogbo.