28 Nitori Oluwa yio mu ọrọ rẹ̀ ṣẹ lori ilẹ aiye, yio pari rẹ̀, yio si ke e kúru li ododo.
29 Ati bi Isaiah ti wi tẹlẹ, Bikoṣe bi Oluwa awọn Ọmọ-ogun ti fi irú-ọmọ silẹ fun wa, awa iba ti dabi Sodomu, a ba si ti sọ wa dabi Gomora.
30 Njẹ kili awa o ha wi? Pe awọn Keferi, ti kò lepa ododo, ọwọ́ wọn tẹ̀ ododo, ṣugbọn ododo ti o ti inu igbala wá ni.
31 Ṣugbọn Israeli ti nlepa ofin ododo, ọwọ́ wọn kò tẹ̀ ofin ododo.
32 Nitori kini? nitori nwọn ko wá a nipa igbagbọ́, ṣugbọn bi ẹnipe nipa iṣẹ ofin. Nitori nwọn kọsẹ lara okuta ikọsẹ ni;
33 Gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Kiyesi i, mo gbé okuta ikọsẹ ati àpata idugbolu kalẹ ni Sioni: ẹnikẹni ti o ba si gbà a gbọ, oju kì yio ti i.