10 Wọ́n gbé ìhámọ́ra Rẹ̀ sí inú ilé tí wọ́n kọ́ fún òrìsà wọn, wọ́n sì fi orí Rẹ̀ kọ́ sí inú ilé Dágónì.
11 Nígbà tí gbogbo àwọn olùgbé Jábésì Gíléádì gbọ́ gbogbo ohun tí àwọn ará Fílístínì ṣe fún Ṣọ́ọ̀lù,
12 Gbogbo àwọn akọni ọkùnrin wọn lọ láti mú àwọn ará Ṣọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọ Rẹ̀, wọ́n sì kó wọn wá sí Jábésì. Nígbà náà, wọ́n sin egungun wọn sábẹ́ igi ńlá ní Jábésì, wọ́n sì gbààwẹ̀ fún ọjọ́ méje.
13 Ṣọ́ọ̀lù kú nítorí kò se òtítọ́ sí Olúwa: Kò pa ọ̀rọ̀ Olúwa mọ́ pẹ̀lú, ó tọ abókúsọ̀rọ̀ lọ fún ìtọ́sọ́nà.
14 Kò sì bèrè lọ́wọ́ Olúwa, bẹ́ẹ̀ ni Olúwa pa á, Ó sì yí ìjọba náà padà sọ́dọ̀ Dáfídì ọmọ Jésè.