1 Kíróníkà 18 BMY

Àwọn Ìṣẹ́gun Dáfídì

1 Ní àkókò kan, Dáfídì kọlu àwọn ará Fílístínì, ó sì sẹ́gun wọn. Ó sì mú Gátì àti àwọn ìlétò agbègbè Rẹ̀ kúrò lábẹ́ ìdarí àwọn ará Fílístínì.

2 Dáfídì borí àwọn ará Móábù, wọ́n sì di ọmọ-ẹ̀yìn Rẹ̀, wọ́n sì mú owó òde wá.

3 Ṣíbẹ̀, Dáfídì bá Hádádáṣérì ọba Ṣóbà jà, jìnnà láti fi ìdarí Rẹ̀ kalẹ̀ lẹ́bàá odò Éúfúrétè.

4 Dáfídì fi agbára gba ẹgbẹ̀rún (1000) kẹ̀kẹ́ Rẹ̀, ẹgbẹ̀rún méje (7,000) a gun kẹ̀kẹ́ àti ẹgbàá méjì ológun ilẹ̀. Ó sì já gbogbo ọgọ́rùn ún iṣan ẹsẹ̀ àwọn kẹ̀kẹ́ ẹsin náà.

5 Nígbá ti àwọn ará Áráméà nì ti Dámásíkù wá láti ran Hadadésérì ọba Ṣóbà lọ́wọ́, Dáfídì lu ẹgbàá méjì wọn bọ lẹ̀.

6 Ó sì fi àwọn ọ̀wọ́ ọmọ-ogun rẹ sínú ìjọba Áráméánì ti Dámásíkù, àwọn ará Áráméánì sì ń sìn ní abẹ́ Rẹ̀, wọ́n sì mú owó ìsákọ́lẹ̀ wá. Olúwa sì ń fún Dáfídì ní ìṣẹ́gun ní ibi gbogbo tí ó bá lọ.

7 Dáfídì mú apata wúrà tí àwọn ìjòyè Hadadésérì gbé, ó sì gbé wọn wá sí Jérúsálẹ́mù.

8 Láti Tébà àti Kúnì, ìlú tí ó jẹ́ ti Hádádéṣérì, Dáfídì mú ọ̀pọ̀ tánganran tí Ṣólómónì lò láti fi ṣe òkun tan-gan-ran, àwọn òpó àti orísìí ohun èlò tan-gan-ran.

9 Nígbà tí Tóù ọba Hámátì gbọ́ pé Dáfídì ti borí gbogbo ọmọ ogun Hádádéṣérì ọba Ṣóbà.

10 Ó rán ọmọ Rẹ̀ Ádórámì sí ọba Dáfídì láti kí i àti láti lọ bá a yọ̀ lórí ìṣẹ́gun Rẹ̀ nínú ogun lórí Hádádéṣérì, tí ó wà lójú ogun pẹ̀lú Tóù. Ádórámì mú oríṣiríṣi ohun èlò ti wúrà àti fàdákà àti tan-gan-ran wá.

11 Ọba Dáfídì ya ohun èlò wọ̀n yí sí mímọ́ fún Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe pẹ̀lú fàdákà àti wúrà tí ó ti mú láti gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè wọ̀nyí: Édómù àti Móábù, ará Ámónì àti àwọn ará Fílístínì àti Ámálékì.

12 Ábíṣáì ọmọ Ṣeruíà, lu méjìdínlógojì ẹgbẹ̀rin ará Édómù bolẹ̀ ní àfonífojì iyọ̀.

13 Ó fi Gárísónì sí Édómù, gbogbo àwọn ará Édómù sì ń sìn ní abẹ́ Dáfídì. Olúwa fún Dáfídì ní ìṣẹ́gun ní gbogbo ibí tí ó bá lọ.

Àwọn Oníṣẹ́ Dáfídì.

14 Dáfídì jọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì, ó sì ṣe òdodo àti ohun tí ó yẹ fún gbogbo àwọn ènìyàn Rẹ̀.

15 Jóábù ọmọ Ṣérúyà jẹ́ olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun; Jéhóṣáfátì ọmọ Áhílúdì jẹ́ akọ̀wé ìrántí;

16 Ṣádókù ọmọ Áhítúbì àti Áhímélékì ọmọ Ábíátarì jẹ́ àwọn àlùfáà; Ṣáfíṣà jẹ́ akọ̀wé;

17 Bénáyà ọmọ Jéhóíádà jẹ́ olórí àwọn kérétì àti pélétì; àwọn ọmọ Dáfídì sì jẹ́ àwọn olóyè onísẹ́ ní ọ̀dọ̀ ọba.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29