1 Kíróníkà 9 BMY

1 Gbogbo Ísírẹ́lì ni a kọ lẹ́sẹsẹ nínú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ àwọn baba ńlá nínú ìwé àwọn ọba Ísírẹ́lì.Àwọn ènìyàn Júdà ni a kó ní ìgbẹ̀kùn lọ sí Bábílónì nítorí àìsòótọ́ wọn.

Àwọn ènìyàn tí ó wà ní Jérúsálẹ́mù.

2 Nísìnsìn yìí, àwọn tí ó kọ́ kọ́ tún tẹ̀dó lórí ohun ìní wọn ní ìlú wọn ni díẹ̀ nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn àlùfáà, àwọn ará Léfì àti àwọn Ìránsẹ́ ilé Olúwa.

3 Àwọn tí ó wá láti Júdà láti Bẹ́ńjámínì àti láti Éfíráímù àti Mánásè tí ó ń gbé ní Jérúsálẹ́mù jẹ́:

4 Hútayì ọmọ Ámíhúdì, ọmọ Ómírì, Ọmọ Ímírì, ọmọ Bánì, ìran ọmọ Fárésì ọmọ Júdà.

5 Tí ará Ṣílò:Ásáíà àkọ́bí àti àwọn ọmọ Rẹ̀.

6 Níti ará Ṣérà:JégúélìÀwọn ènìyàn láti júdà sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ó dín mẹ́wàá (690).

7 Níti ará:Ṣálù ọmọ Mésúlámì, ọmọ Hódáfíà; ọmọ Hásénúà;

8 Íbínéíà ọmọ Jéróhámù; Élà ọmọ Húṣì, ọmọ Míkírì àti Mésúlámù ọmọ Ṣéfátíyà; ọmọ Régúélì, ọmọ Íbíníjà.

9 Àwọn ènìyàn láti Bẹ́ńjámínì gẹ́gẹ́ bí a ti se kọ ọ́ nínú ìran wọn nínú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn, tí ó jẹ́ ẹgbẹ̀rùn ún ó dín mẹ́rìnlélógójì, (956). Gbogbo àwọn ọkùnrin yí jẹ́ àwọn olórí àwọn ìdílé.

10 Ní ti àwọn àlùfáà:Jédáíà; Jéhóíáríbì; Jákínì;

11 Áṣáríyà ọmọ Hílíkíyà, ọmọ Mésúlámù, ọmọ Ṣádókù, ọmọ Méráíótù, ọmọ Áhítúbì, onísẹ́ tí ó ń bojútó ilé Ọlọ́run;

12 Ádáyà ọmọ Jéróhámù, ọmọ Páṣúrì, ọmọ Málíkíjà; àti Másáì ọmọ Ádíélì, ọmọ Jáhíṣérà, ọmọ Mésúlámù ọmọ Méṣílémítì, ọmọ Ímérì

13 Àwọn àlùfáà, tí wọ́n jẹ́ àwọn olórí àwọn ìdílé, tí ó jẹ́ ẹgbẹ̀sán ó dín méjì (1,760). Wọ́n jẹ́ alágbára ọkùnrin, tí wọ́n lè dúró fún iṣẹ́ ìránṣẹ́ nínú ilé Ọlọ́run.

14 Níti àwọn ará Léfì:Ṣémáíà ọmọ Hásíhúbì, ọmọ Ásíríkámù, ọmọ Háṣábíà ará Mérárì:

15 Bákíbákárì, Héréṣì, Gálálì àti Mátaníyà, ọmọ Míkà, ọmọ Ṣíkírì, ọmọ Ásáfù;

16 Ọbadíà ọmọ Ṣémáíà, ọmọ Gálálì, ọmọ Jédútúnì; àti Bérékíà ọmọ Ásà, ọmọ Élíkánà, Tí ó ń gbé nínú àwọn ìlú àwọn ará Nétófá.

17 Àwọn Olùtọ́jú Ẹnu Ọ̀nà:Ṣálúmù, Ákúbù, Tálímónì, Áhímánì àti arákùnrin wọn, Ṣálúmì olóyè wọn,

18 ti wà ní ipò ìdúró ní ẹnu ọ̀nà ọba ní apá ìhà ìlà oòrùn títí di àkókò yí. Wọ̀nyí ni àwọn olùtọ́jú ẹnu ọ̀nà tí ó jẹ́ ti ìpàgọ́ àwọn ará Léfì.

19 Ṣálúmì ọmọ kórè ọmọ Ébíásáfì, ọmọ kórà, àti àwọn olùtọ́jú ẹnu ọ̀nà ẹlẹ́gbẹ́ Rẹ̀. Láti ìdílé Rẹ̀ (àwọn ará kórà) ni ó dúró fún ṣíṣọ́ ìlóró ẹnu ọ̀nà àgọ́ gẹ́gẹ́ bí baba wọn ti ń dúró fún ṣíṣọ́ à bá wọlé ibùgbé Olúwa.

20 Ní ìgbà àkọ́kọ́ fíníhásì ọmọ Élíásérì jẹ́ olórí fún àwọn olùtọ́jú ẹnu ọ̀nà, Olúwa sì wà pẹ̀lú Rẹ̀.

21 Ṣékáríà, ọmọ Méṣélémíà jẹ́ Olùtọ́jú ẹnu ọ̀nà ní à bá wọlé sí àgọ́ ibi ìpàdé.

22 Gbogbo Rẹ̀ lápapọ̀, àwọn tí a yàn láti jẹ́ olùtọ́jú ẹnu ọ̀nà ní àwọn ìlóró ẹnu ọ̀nà jẹ́ ìgba o lé méjìlá (212). A kòmọ̀-ọ́n fún ìràntí nípa ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn ní àwọn ìletò wọn. Àwọn olùtọ́jú ẹnu ọ̀nà ni a ti yàn sí ipò ìgbàgbọ́ wọn láti ọ̀dọ̀ Dáfídì àti Ṣámúẹ́lì aríran.

23 Àwọn àti àtẹ̀lé wọn ni ó wà fún ṣíṣọ́ ẹnu ọ̀nà ilé Olúwa ilé tí a pè ní àgọ́.

24 Àwọn olùtọ́ju ẹnu ọ̀nà wà ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin: ìlà oòrùn, ìwọ̀ oòrùn àríwá àti gúsù.

25 Àwọn arákùnrin wọn ní àwọn ìletò wọn ní láti wá ní àkókò dé àkókò láti pín isẹ́ ìsìn wọn fún àkókò ọjọ́ méje.

26 Ṣùgbọ́n àwọn olórí olùtọ́jú ẹnu ọ̀nà mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí wọ́n jẹ́ ará Léfì ni a yàn fún àwọn iyàrá àti àwọn àpótí ìsúra ní ilé Olúwa.

27 Wọ́n á lo gbogbo òru ní dídúró yí ilé Olúwa ká, nítorí wọ́n ní láti ṣọ́ ọ; Wọ́n sì ní àṣẹ sí kọ́kọ́rọ́ fún ṣíṣí i ní àràárọ̀.

28 Díẹ̀ wà ní ìdí ohun èlò tí à ń lò fún ìsìn ilé Olúwa; wọn a má a kàá nígbà tí wọ́n gbé e wọlé àti nígbà tí a kó wọn jáde.

29 Àwọn mìíràn ni a yàn láti bojútó ohun èlò àti gbogbo ohun èlò ilé tí a yà sọ́tọ̀ fún Ọlọ́run, àti ìyẹ̀fun àti ọtí èso àjàrà àti òróró náà, tùràrí àti tùràrí òlóòórìn dídùn.

30 Ṣùgbọ́n díẹ̀ nínú àwọn àlùfáà ni ó ń bojútó pípo tùràrí olóòórùn dídùn papọ̀.

31 Ará Léfì tí a sọ ní Mátítíhíà, àkọ́bí ọmọkùnrin Ṣálúmì ará kórà ni a yàn sí ìdí dídín àkàrà ọrẹ.

32 Lára àwọn arákùnrin wọn kora wọn wà ní ìdí ṣísètò fún àkàrà tí a máa ń gbé sórí àga tábìlì ní ọjọjọ́ Ìsinmi.

33 Àwọn tí wọ́n jẹ́ ọkùnrin, olórí àwọn ìdílé Léfì dúró nínú àgọ́ ilé Olúwa, wọn kò sì se lára isẹ́ ìsìn yòókù nítorí wọ́n ń se isẹ́ náà lọ́sán, lóru.

34 Gbogbo wọ̀nyí jẹ́ olórí àwọn Léfì, olóyè gẹ́gẹ́ bí a ti se kọ lẹ́sẹsẹ sínú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn, wọ́n sì ń gbé ní Jérúsálẹ́mù.

Ìtàn Ìdílé Láti Ọ̀dọ̀ Baba ńlá wọn, ti Ṣọ́ọ̀lù.

35 Jélíélì baba Gíbíónì ń gbé ní Gíbíónì.Orúkọ ìyàwó Rẹ̀ a má a jẹ́ Mákà,

36 Pẹ̀lú àkọ́bí ọmọkùnrin Rẹ̀ jẹ́ Ábídónì, tí wọ̀nyí sì ń tẹ̀lé Ṣúrì, Kíṣì Bálì, Nérì, Nádábù.

37 Gédórì, Áhíò, Sékaráyà àti Míkílótì.

38 Míkílótì jẹ́ baba Ṣíméámì, àwọn náà ń gbé ní ẹ̀bá ìbátan wọn ní Jérúsálẹ́mù.

39 Nérì jẹ́ baba Kíṣì, Kíṣì baba a Ṣọ́ọ̀lù, àti Ṣọ́ọ̀lù baba a Jónátanì, àti Málíkíṣuà, Ábínádábù àti Éṣí-Bálì.

40 Ọmọ Jónátanì:Méríbú Bálì, tí ó jẹ́ baba a Míkà:

41 Àwọn ọmọ Míkà:Pítónì. Mélékì, Táhíréà àti Áhásì.

42 Áhásì jẹ́ baba Jádà, Jádà jẹ́ baba Álémétì, Aṣimáfétì, Ṣímírì, sì Ṣímírì jẹ́ baba Móṣà.

43 Móṣà jẹ́ baba Bínéà; Réfáíà jẹ́ ọmọ Rẹ̀, Éléásà ọmọ Rẹ̀ àti Áṣélì ọmọ Rẹ̀.

44 Áṣélì ní ọmọ mẹ́fà, pẹ̀lú wọ̀nyí ni orúkọ wọn:Áṣíríkámù, Bókérù, Ísímáélì Ṣéáríà, Óbádíà àti Hánánì Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Áṣélì.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29