1 Kíróníkà 11 BMY

Dáfídì Di Ọba Lórí Ísírẹ́lì

1 Gbogbo àwọn Ísírẹ́lì kó ara wọn jọ pọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ Dáfídì ní Hébúrónì wọ́n sì wí pé, “Àwa ni ẹran ara rẹ àti ẹ̀jẹ̀ rẹ.

2 Ní àtijọ́, kódà nígbà tí Ṣọ́ọ̀lù jẹ ọba, ìwọ ni ẹni tí ó darí Ísírẹ́lì ní ojú ogun wọn. Olúwa Ọlọ́run rẹ sì wí fún ọ pé, ‘Ìwọ yóò sì jẹ́ olùsọ́ àgùntàn fún àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì, ìwọ yóò sì jẹ́ olórí fún wọn.’ ”

3 Nígbà tí gbogbo àwọn ìjòyè Ísírẹ́lì tí wọ́n ti wá sọ́dọ̀ ọba Dáfídì ni Hébúrónì. Ó sì ṣe májẹ̀mú pẹ̀lú wọn ní Hébúrónì níwájú Olúwa, wọ́n sì fi àmìn òróró yan Dáfídì ọba lórí Ísírẹ́lì, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti ṣèlérí láti ọ̀dọ̀ Ṣámúẹ́lì.

Dáfídì Borí Jérúsálẹ́mù.

4 Dáfídì àti gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde lọ sí Jérúsálẹ́mù (tí se Jébúsì) Àwọn ara Jébúsì ẹni tí ń gbé níbẹ̀.

5 Wí fún Dáfídì pé, ìwọ kò sì gbọdọ̀ rí nínú ibẹ̀. Bí ó ti lẹ̀jẹ́ wí pé, Dáfídì kọ lu odi alágbára ti Ṣíónì, ìlú ńlá Dáfídì.

6 Dáfídì ti wí pé Ẹnikẹ́ni tí ó bá darí àti kọlu àwọn ará Jébúsì ni yóò di olórí balógun, Jóábù ọmọ Sérúíà lọ sókè lákòókọ́, bẹ́ẹ̀ ni ó sì gba olórí.

7 Dáfídì sì mú lọ sókè ibùgbé nínú odi alágbára, bẹ́ẹ̀ ní a sì ń pè é ni ìlú Dáfídì.

8 Ó sì kọ́ àwọn ìlú náà yíkákiri Rẹ̀, láti ọ̀dọ̀ àwọn alátìlẹ́yìn ibi ìtẹ́jú ilẹ̀ si àyíká ògiri. Nígbà tí Jóábù sì pa ìyókù àwọn ìlú náà run.

9 Nígbà náà Dáfídì sì jẹ́ alágbára kún alágbára nítorí pé Olúwa àwọn ọmọ ogun wà pẹ̀lú Rẹ̀.

Dáfídì Alágbára Ọkùnrin

10 Àwọn wọ̀nyí sì ni ìjòyè alágbára ọkùnrin Dáfídì, àwọn pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọ́n sì fún ìjọba Rẹ̀ ní àtìlẹ́yìn tó lágbára láti mú un tàn káàkiri gbogbo ilẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sèlérí:

11 èyí sì ni iye àwọn alágbára ọkùnrin Dáfídì:Jásóbéámù ọmọ Hákúmónì, òun sì ni olórí nínú àwọn ìjòyè, ó sì gbé ọ̀kọ̀ Rẹ̀ sókè lórí àwọn ọ̀ọ́dúnrún (300) ènìyàn, àwọn ẹni tí ó pa ní ogun ẹ̀ẹ̀kan.

12 Lẹ́yìn Rẹ̀ sì ni Élíásárì ọmọ Dódáì àwọn ará Áhóhì, ọ̀kan lára àwọn mẹ́ta ọkùnrin alágbára.

13 Ó sì wà pẹ̀lú Dáfídì ní Pásídámímù nígbà tí àwọn ará Fílístínì kó ara wọn jọ láti jagun, níbi tí ilẹ̀ kan wà tí ó kún fún ọkà báálì. Àwọn ènìyàn sì sálọ kúrò níwájú Fílístínì.

14 Ṣùgbọ́n wọ́n mú ìdúró wọn ní àárin pápá náà. Wọ́n sì gbà a wọ́n sì gún àwọn ará Fílístínì mọ́lẹ̀, Olúwa sì mú ìgbàlà ńlá fún wọn.

15 Mẹ́ta nínú àwọn ọgbọ̀n (30) ìjòyè sọ̀kalẹ̀ tọ́ Dáfídì wá lọ sí orí àpáta nínú ìhò Ádúlámù; Nígbà tí àwọn ẹgbẹ́ Fílístínì sì dúró ní àfonífojì ní orí òkè Réfáímù.

16 Ní àsìkò náà Dáfídì sì wà nínú ibi gíga àti àwọn ará Fílístínì modi sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.

17 Dáfídì sí pòǹgbẹ fún omi ó sì wí pé, Áà, ẹnìkan yóò ha buomi láti inú kànga ní ẹ̀gbẹ́ ẹnu bodè Bẹ́tílẹ́hẹ́mù fún un mu?

18 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn mẹ́ta náà sì là láti ogun ará Fílístínì, ó sì fa omi jáde láti inú kànga ní ẹ̀gbẹ́ ẹnu bodè Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ó sì gbé padà tọ Dáfídì wá. Ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti mu ú: dípò, ó sì tú jáde níwájú Olúwa.

19 “Kí Ọlọ́run dẹ́kun kí èmi ó má ṣe se èyí!” ó wí pé. “Se kí èmi kí ó mú ẹ̀jẹ̀ ọkùnrin yí ẹnití ó fi ẹ̀mí Rẹ̀ wéwu?” Nítorí wọ́n fi ẹ̀mí wọn wéwu láti mú padà wá, Dáfídì kò ní mu ú.Nǹkan wọ̀nyí ni àwọn akọni mẹ́ta ọkùnrin náà ṣe ohun ìyanu ńlá.

20 Ábíṣáì arákùnrin Jóábù ìjòyè àwọn mẹ́ta. Ó sì gbé ọ̀kọ̀ Rẹ̀ sókè lórí àwọn ọ̀dúnrún àwọn ènìyàn, àwọn ẹni tí ó pa, bẹ́ẹ̀ ni ó sì di olókìkí gẹ́gẹ́ bí àwọn mẹ́ta.

21 Ó sì gba ìlọ́po ọlá lórí àwọn mẹ́tẹ̀ta ó sì di olórí wọn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò ka kún ara wọn.

22 Bẹ́náyà ọmọ Jéhóíádà ó sì jẹ́ akọni oníjà láti Kábísélì, ẹni tí ó se iṣẹ́ agbára ńlá. Ó sì pa méjì nínú àwọn ọkùnrin tí ó dára jù, ó sì tún sọ̀kalẹ̀ lọ sí inú ihò lákókò sno ó sì pa kìnnìún kan

23 Ó sì pa ara Éjíbítì ẹni tí ó ga ní ìwọ̀n ẹsẹ̀ méje àti ààbọ̀ ṣùgbọ́n àwọn ará Éjíbítì wọn ní ọ̀kọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdubú igi àwunṣọ àti ọ̀pá ní ọwọ́ Rẹ̀, Bénáyà sọ̀kalẹ̀ lórí Rẹ̀ pẹ̀lú kùmọ̀. Ó sì gba ọ̀kọ̀ náà láti ọwọ́ ará Éjíbítì ó sì pa á pẹ̀lú ọ̀kọ̀ Rẹ̀.

24 Nǹkan wọ̀nyí sì ní ìwà akin. Bénáìá ọmọ Jéhóíádà; ohun náà pẹ̀lú sì di ọlálá gẹ́gẹ́ bí àwọn akọni ọkùnrin mẹ́ta.

25 Ó sì ní ọlá púpọ̀ ju àwọn ọgbọ̀n (30) lọ, ṣùgbọ́n a kò káà láàrin àwọn mẹ́tẹ̀ta. Dáfídì sì fi sí ìkáwọ́ àwọn ẹ̀sọ́.

26 Àwọn akọni ọkùnrin náà nìyí:Ásáhélì arákùnrin Jóábù,Élíhánánì ọmọ Dódò láti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù,

27 Ṣámótù ará Hárórì,Hélésì ará Pélónì

28 Írà ọmọ Íkéṣì láti Tékóà,Ábíésérì láti Ánátótì,

29 Ṣíbékíà ará Húṣátì,láti ará Áhóhì

30 Máháráì ará Nétófà,Hélédì ọmọ Báánà ará Nétófà,

31 Ítaì ọmọ Ríbáì láti Gíbéà ní Bẹ́ńjámínì,Bẹ́náyà ará Pírátónì,

32 Húráì láti odò Gáṣì,Ábíélì ará Áríbátì,

33 Ásímáfétì ará BáhárúmùÉlíábà ará Ṣáíbónì

34 Àwọn ọmọ Háṣémù ará GísónìJónátanì ọmọ ṣágè ará Hárárì.

35 Áhíámù ọmọ sákárì ará Hárárì,Élífálì ọmọ Úrì

36 Héférì ará Mékérátì,Áhíjà ará Pélónì,

37 Hésírónì ará KárímélìNáráì ọmọ Ésíbáì,

38 Jóẹ́lì arákùnrin NátanìMíbárì ọmọ Hágárì,

39 Ṣélékì ará Ámónì,Náháráì ará Bérótì ẹni tí ó jẹ́ áru ìhámọ́ra Jóábù ọmọ Ṣérúyà.

40 Írà ará Ítírì,Gárébù ará Ítírì,

41 Húríyà ará HítìṢábádì ọmọ Áháláyì.

42 Ádínà ọmọ Ṣísà ará Réúbẹ́nì, ẹni tí ó jẹ́ ìjòyè ará Réubẹ́nì, àti pẹ̀lú ọgbọ́n Rẹ̀.

43 Hánánì ọmọ Mákà.Jóṣáfátì ará Mítínì.

44 Úsíà ará Ásílérátì,Ṣámà àti Jégiẹ́lì àwọn ọmọ Hótanì ará Áróérì,

45 Jédíáélì ọmọ Ṣímírì,àti arákùnrin Jóhà ará Tísì

46 Élíélì ará MáháfìJéríbáì àti Jóṣáfíà àwọn ọmọ Élánámì,Ítímáì ará Móábù,

47 Élíélì, Óbédì àti Jásídì ará Mésóbà.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29