1 Kíróníkà 1 BMY

Sí Ọmọkùnrin Nóà

1 Ádámù, Ṣétì, Énọ́sì,

2 Kénánì, Máháláléélì, Jérédì,

3 Hénókì, Mètúsẹ́là, Lámékì, Nóà.

4 Àwọn ọmọ Nóà,Ṣémù, Ámù àti Jáfétì.

Àwọn ọmọ Jáfétì

5 Àwọn ọmọ Jáfétì:Gómérì, Mágógù, Mádà; Jáfánì, Túbálì, Méṣékì, Tírásì

6 Àwọn ọmọ Gómérì:Áṣíkénásì, Bífátì, Tógárímà.

7 Àwọn ọmọ Jáfánì:Èlíṣà, Tárísísì, Kítímù, àti Dódánímù.

Àwọn ọmọ Ámù

8 Àwọn ọmọ Ámù:Kúṣì, Ṣébà, Mísíráímù, Pútì, àti Kénánì.

9 Àwọn ọmọ Kúṣì:Ṣébà Háfílà, Ṣébítà, Rámà, àti Ṣábítékà,Àwọn ọmọ Rámà:Ṣébà àti Dédánì.

10 Kúṣì ni baba Nímíródù:Ẹni tí ó dàgbà tí ó sì jẹ́ jagunjagun alágbára lórí ilẹ̀ ayé.

11 Mísíráímù ni babaLúdímù, Ánámímù, Léhábímù, Náfítúhímù,

12 Pátírísímù, Kásiliúhímù, (Láti ọ̀dọ̀ ẹni tí àwọn ará Fílístínì ti wá) àti Káfitórímù.

13 Kénánì ni babaṢídónì àkọ́bí Rẹ̀, àti ti àwọn ará Hítì,

14 Àwọn ará Jébúsì, àwọn ará Ámórì, àwọn ará Gírígásì

15 Àwọn Hífì, àwọn ará Áríkì, àwọn ará Hamati-Ṣínì,

16 Àwọn ará Árífádù, àwọn ará, Ṣémárì, àwọn ará Hámátì.

Àwọn Ará Ṣémù.

17 Àwọn ọmọ Ṣémù:Élámù. Ásúrì, Árífákásádì, Lúdì àti Árámù.Àwọn ará Árámù:Usì Húlì, Gétérì, àti Méṣékì.

18 Árífákásádì sì jẹ́ Baba Ṣélà,àti Ṣélà sì jẹ́ Baba Ébérì.

19 A bí àwọn ọmọ méjì fún Ébérì:Orúkọ ọ̀kan ni Pélégì, nítorí ní àkókò tirẹ̀ a pín ayé; orúkọ ẹ̀gbọ́n Rẹ̀ ọkùnrin a sì máa jẹ́ Jókítanì.

20 Jókítanì sì jẹ́ Baba fúnHímódádì, Ṣéléfì, Hásárímáfétì, Jérà.

21 Hádórámì, Úsálì, àti Díkílà

22 Ébálì, Ábímáélì, Ṣébà.

23 Ófírì, Háfílà, àti Jóbábù. Gbogbo àwọn wọ̀nyí sì jẹ́ àwọn ọmọ Jókítanì.

24 Ṣémù, Árífákásádì, Sẹ́bà,

25 Ébérì, Pélégì. Réù,

26 Ṣérúgì, Náhórì, Térà:

27 Àti Ábúrámù (tí ń ṣe Ábúráhámù).

Ìdílé Ábúráhámù

28 Àwọn ọmọ Ábúráhámù:Ísáákì àti Íṣímáẹ́lì.

Àwọn ọmọ Hágárì

29 Èyí ni àwọn ọmọ náà:Nébáíótì àkọ́bí Íṣímáẹ́lì: Kédárì, Ádíbélì, Míbísámù,

30 Míṣímà, Dúmà, Másà, Hádádì, Témà,

31 Jétúrì, Náfísì, àti Kédámù. Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Íṣímáẹ́lì

Àwọn ọmọ Kétúrà

32 Àwọn ọmọ Kétúrà, obìnrin Ábúráhámù:Símíránì, Jókíṣánì Médánì, Mídíánì Iṣíbákì àti Ṣúà.Àwọn ọmọ Jókísánì:Ṣébà àti Dédánì.

33 Ọmọ Mídíánì:Éfà. Hénókì, Éférì, Ábídà àti Élídà.Gbogbo àwọn wọ̀nyí ni ìran Kétúrà.

Àwọn Ìran Ṣárà

34 Ábúráhámù sì jẹ́ baba Ísáákì:Àwọn ọmọ Ísáákì:Ísọ̀ àti Ísírẹ́lì.

Àwọn Ọmọ Ísọ̀

35 Àwọn ọmọ Ísọ̀:Élífásì, Réuélì, Jéúsì, Jálámù, àti Kórà.

36 Àwọn ọmọ Élífásì:Témánì, Ómárì, Ṣéfì, Gátamù àti Kénásì;làti Tímánà: Ámálékì.

37 Àwọn ọmọ Réúélì:Náhátì, Ṣérà, Ṣámà àti Mísà.

Àwọn Ènìyàn Ṣéírì Ní Édómù

38 Àwọn ọmọ Ṣéírì:Lótanì, Ṣóbálì, Ṣíbéónì, Ánà, Díṣónì, Ésárì àti Dísánì.

39 Àwọn ọmọ Lótanì:Hórì àti Hómámù. Tímínà sì jẹ́ arábìnrin Lótanì.

40 Àwọn ọmọ Ṣóbálì:Álíánì, Mánánátì, Ébálì, Ṣéfì àti Ónámù.Àwọn ọmọ Ṣíbéónì:Áíyà àti Ánà.

41 Àwọn ọmọ Ánà:Díṣónì.Àwọn ọmọ Díṣónì:Hémídánì, Éṣébánì, Ítíránì, àti Kéránì.

42 Àwọn ọmọ Èsérì:Bílíhánì, Ṣáfánì àti Jákánì.Àwọn ọmọ Díṣánì:Húsì àti Áránì.

Àwọn Alákóso Édómù

43 Àwọn wọ̀nyí ni ọba tí ó jẹ ní Édómù, kí ó tó di wí pé àwọn ọba ará Ísírẹ́lì kán jẹ:Bélà ọmọ Béórì, ẹni tí orúkọ ìlú Rẹ̀ a máa jẹ́ Díníhábà.

44 Nígbà tí Bélà kú, Jóbábù ọmọ Ṣérà láti Bósírà jẹ ọba dípò Rẹ̀.

45 Nígbà tí Jóbábù sì kú, Húṣámù láti ilẹ̀ àwọn ará Témánì sì jẹ ọba ní ipò Rẹ̀.

46 Nígbà tí Húṣámù sì kú, Hádádì ọmọ Bédádì, ẹni tí ó kọlu Mídíánì ní agbégbé Móábù, ó sì jẹ ọba ní ipò Rẹ̀. Orúkọ ìlú Rẹ̀ sì ni Áfítì.

47 Nígbà tí Hádádì sì kú, Ṣámílà láti Másírékà, ó sì jọba ní ipò Rẹ̀

48 Nígbà tí Ṣámílà sì kú, Ṣáúlì láti Réhóbótì lórí odò sì jẹ ọba ní ipò Rẹ̀

49 Nígbà tí Ṣáúlì sì kú, Báli-hánánì, ọmọ Ákíbórì sì jẹ ọba ní ipò Rẹ̀.

50 Nígbà tí Báli-hánánì sì kú, Hádádì sì di ọba nípò Rẹ̀. Orúkọ ìlú Rẹ̀ sì ni Páì; àti orúkọ ìyàwó sì ni Méhélábélì ọmọbìnrin Métírédì, ọmọbìnrin Mésíhábù.

51 Hádádì sì kú pẹ̀lú.Àwọn olórí Édómù ni:Tímínà, Álífà, Jététì

52 Óhólíbámà, Élà, Pínónì.

53 Kénásì, Témánì, Mísárì,

54 Mágádíẹ́lì àti Ìrámù. Àwọn wọ̀nyí ni Olórí Édómù.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29