1 Nígbà tí ó di ọdún kẹsàn án ìjọba Ṣédékíàyà. Ní ọjọ́ kẹwàá oṣù kẹwàá, Nebukadinésárì ọba Bábílónì yan lọ sí Jérúsálẹ́mù pẹ̀lú gbogbo àwọn ogun rẹ̀. Ó sì pàgọ́ sí ìta ìlú ó sì mu àwọn isẹ ìdọ̀tì fi yí gbogbo rẹ̀ ká.
2 Ìlú náà sì wà ní ìhámọ́ lábẹ́ ìdọ̀tí títí di ọdún kọkànlá ti ọba Ṣédékíáyà.
3 Nígbà tí ó di ọjọ́ kẹsàn-án oṣù kẹrin, iyàn tí mú ní ìlú tí ó jẹ́ wí pé kò sí oúnjẹ fún àwọn ènìyàn láti jẹ.
4 Nígbà náà odi ìlú náà sì fón ká, gbogbo àwọn ọmọ ogun sá lọ ní òru láti ẹnu ọ̀nà bodè láàrin ògiri méjì ní ẹgbẹ́ ọgbà ọba, lára àwọn ará Bábílónì wọ́n sì yí ìlú náà ká. Wọ́n sá lọ sí ìkọjá Árábù.
5 Ṣùgbọ́n ogun àwọn ará kalídíà sì lépa ọba, wọ́n sì lée bá ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jéríkò. Gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sì yà kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì túká,
6 Wọ́n sì mú un wọ́n sì mú lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Bábílónì ní Ríbílà, níbi tí à ti ṣe ìdájọ́ lórí rẹ̀.
7 Wọ́n sì pa ọmọ Ṣédékáyà níwájú rẹ̀, wọ́n sì yọ ojú rẹ̀ jáde, wọn dèé pẹ̀lú ẹ̀wọ̀n idẹ wọ́n sì gbe é lọ sí Bábílónì.
8 Ní ọjọ́ kèje ní oṣù karùn ún, ní ọdún ìkọkàndínlógún ti Nebukadinésárì ọba Bábílónì, Nebukadinéṣárì olórí ẹ̀sọ́ ti ọba ìjòyè ọba Bábílónì wá sí Jérúsálẹ́mù
9 ó sì finá sí ilé Olúwa, ilé ọba àti gbogbo àwọn tí ó wà ní Jérúsálẹ́mù àti gbogbo ilé pàtàkì, ó jó wọn níná.
10 Gbogbo àwọn ọmọ ogun Bábílónì, lábẹ́ olórí ti ìjọba ẹ̀sọ́, wó ògiri tí ó yí Jérúsálẹ́mù ká lulẹ̀.
11 Nebukadinésárí olórí ẹ̀ṣọ́ Kó lọ sí ìgbékùn gbogbo ènìyàn tí ó kù ní ìlú, àti àwọn Ísánsà àti àwọn tí ó ti lo sí ọ̀dọ̀ ọba Bábílón.
12 Ṣùgbọ́n olórí ẹ̀sọ́ fí àwọn talákà ènìyàn ilẹ̀ náà sílẹ̀ láti ṣiṣẹ́ nínú ọgbà àti orí pápá.
13 Àwọn ará Bábílónì fọ́ ọwọ́n idẹ sí túútúú, àti ìjòkòó àti agbada ńlá idẹ tí ó wà nílé Olúwa wọ́n sì kọ́ idẹ wọn sí Bábílónì.
14 Wọ́n sì kóo lọ pẹ̀lú àwo ìkòkò ọkọ́, àlùmágàjí fìtílà, síbí àti gbogbo ohun èló idẹ tí wọ́n lò nílé tí wọ́n fi sisẹ́.
15 Olórí ìjọ̀ba ẹ̀sọ́ mu ìfọnná, àti ọpọ́n, èyí tí wọ́n fi wúrà àti Sílifà ṣe lọ.
16 Bàbà méjì láti ara ọ̀wọ̀n òkú àti ìjòkòó, tí Ṣólómónì ti ṣe fún ilé Olúwa, ó ju èyí tí a lé wọ́n lọ.
17 Ọ̀kọ̀ọ̀kan ọ̀wọ̀n gíga rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ ẹsẹ̀ méjìlélógún Olórí Bàbà lórí ọkẹ ọ̀kọ̀ọ̀kan ọ̀wọ̀n ọ̀gá ni ìwọ̀n mẹ́rin àti ààbò wọn sì ṣe lọ́sọ́ọ̀ pẹ̀lú iṣe àwọ̀n àti àwọ pòmégránátè tí ó wà lórí ọ̀nà orí gbogbo rẹ̀ yíká, ọ̀wọ̀n mìíràn, pẹ̀lú iṣẹ́ híhun, wọ́n sì kéré.
18 Olórí àwọn ọ̀sọ́ sì mú gẹ́gẹ́ bí olórí àwọn ẹlẹ́wọ̀n Ṣéráíáyà olórí àwọn àlùfáà, Ṣéfáníà àlùfáà ẹni tí ó kù nínú oyè gíga àti àwọn olùṣọ́nà mẹ́ta.
19 Àti àwọn tí ó kù ní ìlú, ó mú ìjòyè tí ó fi sí ipò olórí àwọn ológun ọkùnrin àti àwọn agbà oní ní ìmọ̀ràn ọba. Ó sì tún mú akọ̀wé tí ó jẹ́ ìjòyè tí ń to àwọn ènìyàn ilé náà àti mẹ́fà nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ tí wọ́n rí ní ìlú.
20 Nebukadínésárì olórí àwọn ẹ̀sọ́ kó gbogbo wọn, ó sì mú wọn wá sí ọ̀dọ̀ ọba Bábílónì ní Ríbílà.
21 Níbẹ̀ ní Ríbílà, ní ilẹ̀ Hámátì, ọba sì kọlù wọ́n, bẹ́ẹ̀ ni Júdà lọ sí oko ẹrú, kúrò láti ilé rẹ̀.
22 Nebukadínésárì ọba Bábílónì ó mú Gédalíàh ọmọ Áhíkámù ọmọ ṣáfánì, láti jọba lórí àwọn ènìyàn tí ó ti fa kalẹ̀ lẹ́yìn ní Júdà.
23 Nígbà tí gbogbo àwọn olórí ogun àti àwọn ọkùnrin wọn gbọ́ pé ọba Bábílónì ti yan Gédálíàh gẹ́gẹ́ bí baálẹ̀, wọ́n wá sí ọ̀dọ̀ Gédálíàh ni Mísípà. Ísímáélì ọmọ Nétaníàh, Jóhánánì ọmọ Káréà, Séráíáyà ọmọ Tánhúmétì ará Nétófátì, Jásáníáyà ọmọ ara Mákà, àti àwọn ọkùnrin wọn.
24 Gédálíà sì búrà láti fi dá àwọn ènìyàn rẹ̀ lójú. “Ẹ má ṣe bẹ̀rù àwọn ìjòyè ará káidéà,” ó wí pé, “Ẹ máa gbé ilẹ̀ náà kí ẹ sì sin ọba Bábílónì, yóò sì dára fún un yín.”
25 Ní oṣù kèje, bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé, Ísmáélì ọmọ Nétaníáyà, ọmọ Èlísámà, ẹni tí ó jẹ́ ti ẹ̀jẹ̀ ọba, wá pẹ̀lú àwọn ọkùnrin mẹ́wàá ó sì kọlù Gédálíáyà àti pẹ̀lú àwọn ọkùnrin mẹwàá ará Júdà àti àwọn ará káídéà tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ ní Míspà.
26 Nítorí èyí, gbogbo àwọn ènìyàn láti ẹni kékeré títí dé ẹni ńlá, àti pẹ̀lú àwọn olórí ogun, sá lọ si Éjíbítì nítorí ẹ̀rù àwọn ará Bábílónì.
27 Ní ọdún kẹtàdínlógójì tí a lé Jéhóíákínì ọba Júdà kúrò nílú, ní ọdún tí Efili-Méródákì di ọba Bábílónì, ó tú Jéhóíákínì kúrò nínú túbú ní ọjọ́ kẹtàdínlógbọ̀n oṣú kéjìlá.
28 Ó sì sọ̀rọ̀ dáradára ó sì fún ún ní ìjòkòó tí ó ga lọ́lá jùlọ ju gbogbo àwọn ọba tó kù tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ ní Bábílónì lọ,
29 Bẹ́ẹ̀ ni Jéhóíákínì fi sí ẹ̀gbẹ́ kan àwọn aṣọ́ túbú àti fún gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ tí ó ku oúnjẹ ó ń jẹ, nígbà gbogbo ní orí tabílì ọba.
30 Ní ojoojúmọ́ ọba fún Jéhóíákínì ní ohun tí ó yọ̀ǹda nígbà kúgbà gẹ́gẹ́ bí ó tí ń bẹ láàyè.