2 Ọba 9 BMY

A fi àmì òróró yàn Jéhù ní ọba Ísírẹ́lì.

1 Wòlíì Èlíṣà fi àṣẹ pe ọkùnrin kan láti ẹgbẹ́ àwọn wòlíì, ó sì wí fún un pé, “Ki agbádá rẹ sínú ọ̀já àmùrè rẹ, gba ṣágo kékeré òróró yìí pẹ̀lú rẹ, kí o sì lọ sí Ramoti-Gílíádì.

2 Nígbà tí o bá dé bẹ̀, wá Jéhù ọmọ Jéhóṣáfátì, ọmọ Mímísì kiri. Lọ sí ọ̀dọ̀ ọ rẹ̀, mú un kúrò lọ́dọ̀ àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀, kí o sì mú un wọ inú yàrá lọ́hùn ún lọ.

3 Nígbà náà, mú ṣágo kékeré yìí, kí o sì da òróró náà lé e lórí, kí o sì wí pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí: Èmi fi àmì òróró yàn Ọ́ ní ọba lórí Ísírẹ́lì.’ Nígbà náà, sí ìlẹ̀kùn, kí o sì sáré; Má ṣe jáfara!”

4 Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀dọ́mọkùnrin náà, wòlíì náà lọ sí Ramoti-Gílíádì.

5 Nígbà tí ó dé, ó rí àwọn olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun tí wọ́n jókòó papọ̀. “Èmi ní iṣẹ́ fún ọ, olórí,” Ó wí.“Fún èwo nínú wa?” Jéhù béèrè.“Fún ọ, Alákóso,” Ó dáhùn.

6 Jéhù dìde sókè, ó sì wọ inú ilé lọ. Nígbà náà, wòlíì náà da òróró náà sórí Jéhù; ó sì wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: ‘Èmi fi àmì òróró yàn ọ́ ní ọba lórí àwọn ènìyàn Olúwa Ísírẹ́lì.

7 Kí ìwọ kí ó pa ilé Áhábù ọ̀gá à rẹ̀ run, Èmi yóò sì gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ gbogbo àwọn ìránṣẹ́ mi wòlíì àti gbogbo ẹ̀jẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ Olúwa tí a ta sílẹ̀ látọwọ́ ọ Jésébélì.

8 Gbogbo ilé Áhábù yóò ṣègbé. Èmi yóò gé e kúrò láti orí Áhábù gbogbo ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó gbẹ̀yìn ni Ísírẹ́lì, ẹrú tàbí òmìnira.

9 Èmi yóò ṣe ilé Áhábù gẹ́gẹ́ bí ilé Jéróbóhámù ọmọ Nábátì àti ilé Bááṣà ọmọ Áhíjà.

10 Fún Jésébélì, ajá ni yóò jẹ ẹ́ ní oko Jésírẹ́lì, kò sì sí ẹni tí yóò sin òkúrẹ̀.’ ” Nígbà náà ó sí ìlẹ̀kùn, ó sì sálọ.

11 Nígbà tí Jéhù jáde lọ bá àwọn ọgbà ìjòyè e rẹ̀, ọ̀kan nínú wọn sì bi í pé, “Ṣé gbogbo nǹkan dára?”Kí ni ó dé tí aṣiwèrè fi tọ̀ ọ́ wá, “Ìwọ mọ ọkùnrin náà àti irú nǹkan tí ó ń sọ,” Jéhù fèsì.

12 “Ìyẹn kì í ṣe òótọ́!” Wọ́n wí. “Ṣọ fún wa.”Jéhù wí, “Èyí ni ohun tí ó sọ fún mi: ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí: Èmi fi àmì òróró yàn ọ́ ní ọba lórí Ísírẹ́lì.’ ”

13 Wọ́n ṣe gírì, wọ́n sì mú agbádá a wọn, wọ́n sì tàn wọ́n sí abẹ́ rẹ̀ ní órí àtẹ̀gùn. Nígbà náà, wọ́n fọn ipè, wọ́n sì kígbe, “Jéhù jẹ ọba!”

Jéhù pa Jórámù àti Áhásáyà.

14 Bẹ́ẹ̀ ni Jéhù ọmọ Jéhósáfátì, ọmọ Nímsì, dìtẹ̀ sí Jórámù. (Nísinsìnyí Jórámù àti gbogbo Ísírẹ́lì ti ń dábòbò Ramoti-Gílíádì nítorí Hásáélì ọba Árámù:

15 Ṣùgbọ́n ọba Jórámù ti padà sí Jéṣérẹ́lì láti lọ sàn nínú ọgbẹ́ tí àwọn ará Árámù ti dá sí i lára nínú ogun pẹ̀lú ọba Hásáélì ti Árámù). Jéhù wí pé, “Tí èyí bá jẹ́ ọ̀nà tí ò ń rò, má ṣe jẹ́ kí ẹnìkankan kí ó yọ jáde nínú ìlú ńlá láti lọ sọ ìròyìn náà ní Jéṣérẹ́lì.”

16 Nígbà náà ó wọ inú kẹ̀kẹ́ rẹ̀, ó sì gùn ún lọ sí Jésérẹ́lì, nítorí Jórámù ń sinmi níbẹ̀ àti ọba Áhásáyà tilọ láti lọ wò ó.

17 Nígbà tí olùṣọ́ kan tí ó dúró ní ilé ìṣọ́ ní Jésérẹ́lì, rí ọ̀wọ́-ogun Jéhù tí wọ́n ń súnmọ́ tòsí, ó pè jáde, “Mo rí àwọn ọ̀wọ́ ogun tí ó ń bọ̀.”“Mú ọkùnrin ẹlẹ́ṣin kan,” Jórámù pa á láṣẹ. “Rán an lọ sí ọ̀dọ̀ wọn kí o sì béèrè pé, ‘Ṣé ẹ̀yin wá pẹ̀lú àlàáfíà?’ ”

18 Ọkùnrin ẹlẹ́ṣin náà, lọ láti lọ bá Jéhù ó sì wí pé, “Èyí ni ohun tí ọba wí: ‘Ṣé ìwọ wá pẹ̀lú àlàáfíà?’ ”“Kí ni ìwọ ní ṣe pẹ̀lú àlàáfíà?” Jéhù sì dáhùn. “Ṣubú sími lẹ́yìn.”Olùṣọ́ náà sì wí fún un pé, “Ìránṣẹ́ náà ti dé ọ̀dọ̀ wọn, ṣùgbọ́n kò tún padà wá mọ́.”

19 Bẹ́ẹ̀ ni, ọba rán ọkùnrin ẹlẹ́ṣin kejì, Nígbà náà ó wá sí ọ̀dọ̀ wọn, ó wí pé, “Èyí ni ohun tí ọba sọ:“Ṣé ìwọ wá pẹ̀lú àlàáfíà?” Jéhù dáhùn, “Ṣúbu sími lẹ́yìn.”

20 Olùṣọ́ náà sì fi sùn. “Ó ti dé ọ̀dọ̀ wọn, ṣùgbọ́n kò tún padà wá mọ́ pẹ̀lú. Wíwá rẹ̀ sì dàbí ti Jéhù ọmọ Nímsì, ó ń wa kẹ̀kẹ́ bí ti aṣiwèrè.”

21 “Fi ìwọ̀ kọ́ kẹ̀kẹ́ ogun mi.” Jórámù pa á láṣẹ. Àti nígbà tí a fi kọ́, Jórámù ọba Ísírẹ́lì àti Áhásáyà ọba Júdà, gun kẹ̀kẹ́ lọ, olúkúlùkù nínú kẹ̀kẹ́ ogun tirẹ̀, láti lọ bá Jéhù. Wọ́n bá a pàdé ní ibi oko tí ó ti jẹ́ ti Nábótì ará Jéṣírẹ́lì.

22 Nígbà tí Jórámù rí Jéhù, ó béèrè pé, “Ṣé ìwọ wá pẹ̀lú àlàáfíà, Jéhù?”“Báwo ni àlàáfíà yóò ṣe wà,” Jéhù dáhùn, “Ní ìwọ̀n ìgbà tí gbogbo ìbọ̀rìṣà àti iṣẹ́ àjẹ́ ti mọ̀mọ́ rẹ Jésébélì di púpọ̀?”

23 Jórámù yípò padà, ó sì sá lọ ó sì ń pe Áhásáyà, “ó ṣe ìwà àrékérekè, Áhásáyà!”

24 Nígbà náà, Jéhù fa ọrun rẹ̀, ó sì yin Jórámù láàárin èjìká méjèèjì. Ọfà náà sì wọ inú ọkàn rẹ̀, ó sì ṣubú lulẹ̀ láti orí kẹ̀kẹ́ rẹ̀.

25 Jéhù sọ fún Bídíkárì, balógun kẹ̀kẹ́ ẹ rẹ̀ pé, “Gbé e sókè kí ó sì jù ú sí orí pápá tí ó jẹ́ ti Nábótì ará Jésérẹ́lì. Rantí bí èmi àti ìwọ ti ń gun kẹ̀kẹ́ papọ̀ lẹ́yìn Áhábù bàbá à rẹ nígbà tí Olúwa sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀:

26 ‘Ní àná, mo rí ẹ̀jẹ̀ Nábótì pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, ni Olúwa wí.’ Ǹjẹ́ nítorí náà, ẹ gbé e sókè, kí o sì jù ú sí orí ilẹ̀ oko náà ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Olúwa.”

27 Nígbà tí Áhásáyà ọba, Júdà rí ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀, ó sálọ sójú ọ̀nà sí Bẹti-Hágánì. Jéhù sì lépa rẹ̀, ó ń kígbe, “Pa á pẹ̀lú!” Wọ́n sá a ní ọgbẹ́ nínú kẹ̀kẹ́ ẹ rẹ̀ ní ọ̀nà lọ sí Gúrì lẹ́bà a Íbíléámù, ṣùgbọ́n ó sálọ sí Mégídò, ó sì kú síbẹ̀.

28 Ìránṣẹ́ rẹ̀ sì gbé e pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ lọ sí Jérúsálẹ́mù, ó sì sin ín pẹ̀lú, bàbá a rẹ̀ nínú ibojì rẹ̀ ní ìlú ńlá ti Dáfídì.

29 (Ní ọdún kọkànlá ti Jórámù ọmọ Áhábù, Áhásáyà ti di ọba Júdà.)

A pa Jésébélì

30 Nígbà náà Jéhù lọ sí Jésérẹ́lì. Nígbà tí Jésébélì gbọ́ nípa rẹ̀, ó kun ojú u rẹ̀, ó to irun rẹ̀, ó sì wò jáde láti ojú fèrèsé.

31 Bí Jéhù ti wọ ẹnu ìlẹ̀kùn, ó béèrè, “Ṣé ìwọ wá lálàáfíà, Símírì, ìwọ olùpa ọ̀gá à rẹ?”

32 Ó gbójú sókè láti wo fèrèsé, ó sì pè jáde, “Ta ni ó wà ní ẹ̀gbẹ́ mi? Ta ni?” Ìwẹ̀fà méjì tàbí mẹ́ta bojú wò ó nílẹ̀.

33 Jéhù sọ wí pé, “Gbé e jùsílẹ̀ wọ́n sì jù ú sílẹ̀!” Díẹ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sì fọ́n sí ara ògiri àti àwọn ẹṣin bí wọ́n ti tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀ wọn.

34 Jéhù wọ inú ilé lọ, ó jẹ ó sì mu. “Tọ́jú obìnrin yẹn tí a fi bú,” Ó wí, “Kí o sì sin-ín, nítorí ọmọbìnrin ọba ni ó jẹ́.”

35 Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n jáde lọ láti lọ sin-ín, wọn kò rí nǹkankan àyàfi agbárí i rẹ̀, ẹsẹ̀ rẹ̀ méjèèjì àti ọwọ́ ọ rẹ̀ méjèèjì.

36 Wọ́n padà lọ sọ fún Jéhù, ẹni tí ó wí pé, “Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó sọ nípasẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀ Èlíjà ará Tíṣíbì wí pé: Ní orí oko Jésérẹ́lì ni àwọn ajá yóò ti jẹ ẹran ara Jésébélì.

37 Òkú Jésébélì yóò dàbí ohun ẹ̀gbin ní orí oko Jésérẹ́lì, débi pé, ẹnikẹ́ni kì yóò lè sọ pé, ‘Jésébélì ni èyí.’ ”

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25