1 Ní ọdún kẹtàdínlọ́gbọ̀n tí Jéróbóámù ọba Ísírẹ́lì, Ásáríyà ọmọ Ámásáyà ọba Júdà sì bẹ̀rẹ̀ sí ní jọba.
2 Ó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rindínlógún nígbà tí o di ọba, ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún méjìléláàdọ́ta. Orúkọ ìyá a rẹ̀ a má a jẹ́ Jékólíà; ó wá láti Jérúsálẹ́mù.
3 Ó ṣe ohun tí ó dára lójú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí baba rẹ̀ Ámásáyà ti ṣe.
4 Àwọn ibi gíga, bí ó ti wù kí ó rí, a kò sí wọn kúrò; Àwọn ènìyàn náà tẹ̀ṣíwájú láti máa rú ẹbọ àti sun tùràrí níbẹ̀.
5 Olúwa sì kọlu ọba náà pẹ̀lú ẹ̀tẹ̀, títí di ọjọ́ tí ó kú, ó sì ń gbé ní ilé ọ̀tọ̀. Jótamì, ọmọ ọba sì tọ́jú ààfin, ó sì ń darí àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà.
6 Fún ti ìyókù iṣẹ́ nígbà ìjọba Ásáríyà, pẹ̀lú gbogbo ohun tí ó ṣe, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Júdà.
7 Ásáríyà sinmi pẹ̀lú àwọn baba a rẹ̀. A sì sin ín sí ẹ̀bá wọn ní ìlú ńlá ti Dáfídì. Jótamì ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.
8 Ní ọdún kejìdínlógójì Ásáríyà ọba Júdà. Ṣakaríà ọmọ Jéróbóámù di ọba Ísírẹ́lì ní Ṣamáríà, ó sì jọba fún oṣù mẹ́fà.
9 Ó ṣe búburú lójú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí àwọn baba rẹ̀ tí ṣe. Kò sì yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jéróbóámù ọmọ Nébátì, èyí tí ó ti fa Ísírẹ́lì láti dá.
10 Ṣálúmù ọmọ Jábésì dìtẹ̀ sí Ṣakaríà. Ó dojúkọ ọ́ níwájú àwọn ènìyàn, ó sì pa á, ó sì jọba dípò rẹ̀.
11 Fún ti ìyókù iṣẹ́ nígbà ìjọba Ṣakaríà. Wọ́n kọ ọ́ sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Ísírẹ́lì.
12 Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí a sọ fún Jéhù jẹ́ ìmúṣẹ: “Àwọn ọmọ rẹ̀ yóò jókòó lórí ìtẹ́ Ísírẹ́lì títí dé ìran kẹrin.”
13 Ṣálúmù ọmọ Jábésì di ọba ní ọdún kọkàndínlógójì Ùsáyà ọba Júdà, ó sì jọba ní Ṣamáríà fún oṣù kan.
14 Nígbà náà Ménáhémù ọmọ Gádì lọ láti Tírísà sí Ṣamáríà. Ó dojúkọ Ṣalúmù ọmọ Jábésì ní Samáríà, ó pa á ó sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.
15 Fún ti ìyókù iṣẹ́ ìjọba Ṣalúmù, àti ìdìtẹ̀ tí ó dì, a kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Ísírẹ́lì.
16 Ní ìgbà tí Ménáhémù ń jáde bọ̀ láti Tíríṣà, ó dojúkọ Tífíṣà àti gbogbo ènìyàn tí ó wà ní ìlú ńlá àti agbègbè rẹ̀, Nítorí wọn kọ̀ láti sí ẹnu ibodè. Ó yọ Tífsà kúrò lẹ́nu iṣẹ́, ó sì la inú gbogbo àwọn obìnrin aboyún.
17 Ní ọdún kọkàndínlógójì ti Ásáríyà ọba Júdà, Ménáhémù ọmọ Gádì di ọba Ísírẹ́lì, ó sì jọba ní Samáríà fún ọdún mẹ́wàá.
18 Ó ṣe búburú lójú Olúwa, ní gbogbo ìjọba rẹ̀. Kò sì yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jéróbóámù ọmọ Nébátì, èyí tí ó ti fa Ísírẹ́lì láti dá.
19 Nígbà náà, Púlù ọba Ásíríà, gbógun ti ilẹ̀ náà, Ménáhémù sì fún un ní ẹgbẹ̀rin talẹ́ńtì fàdákà láti fi gba àtìlẹyìn rẹ̀ àti láti fún ìdúró tirẹ̀ lágbára lórí ìjọba.
20 Ménáhémù fi agbára gba owó náà lọ́wọ́ Ísírẹ́lì. Gbogbo ọkùnrin ọlọ́lá ní láti dá àádọ́ta ṣékélì fàdákà láti fún ọba Áṣíríà. Bẹ́ẹ̀ ni ọba Áṣíríà padà sẹ́yìn, kò sì dúró ní ilẹ̀ náà mọ́.
21 Fún ti ìyókù iṣẹ́ nígbà ìjọba Ménáhémù, àti gbogbo ohun tí ó ṣe, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé ọba Ísírẹ́lì?
22 Ménáhémù sinmi pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀. Pékáhíà ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.
23 Ní ọdún kẹẹ̀dógún Ásáríyà ọba Júdà, Pékáhíà ọmọ Ménáhémù di ọba Ísírẹ́lì ní Ṣamáríà, ó sì jọba fún ọdún méjì.
24 Pékáhíà ṣe búburú lójú Olúwa. Kò yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jéróbóámù ọmọ Nébátì, èyí tí ó fa Ísírẹ́lì láti dá.
25 Ọ̀kan lára àwọn olórí ìjòyè rẹ̀ Pékà ọmọ Remalíà, dìtẹ̀ síi. Ó mú àádọ́ta àwọn ọkùnrin ti àwọn ará Gílíádì pẹ̀lú u rẹ̀. Ó pa Pékáhíà pẹ̀lú Árígóbù àti Áríè ní Kítadélì ti ààfin ọba ní Ṣamáríà. Bẹ́ẹ̀ ni Pékà pa Pékáhíà, ó sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.
26 Fún ti ìyókù iṣẹ́ ìjọba Pékáhíà, gbogbo ohun tí ó ṣe, ni a kọ sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Ísírẹ́lì
27 Ní ọdún kejìléláàdọ́ta Ásáríyà ọba Júdà, Pékà ọmọ Rèmálíà di ọba Ísírẹ́lì ní Ṣamáríà. Ó sì jọba fún ogún ọdún.
28 Ó sì ṣe búburú lójú Olúwa, kò sì yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jéróbóámù ọmọ Nébátì, èyí tí ó fa Ísírẹ́lì láti dá.
29 Ní ìgbà Pékà ọba Ísírẹ́lì, Tígílátì Pílésérì ọba Ásíríà wá, ó sì mú Íjónì, Abeli-Bẹti-Máákà, Jánóà, Kédéṣì àti Hásórì. Ó gba Gíléádì àti Gálílì pẹ̀lú gbogbo ilẹ̀ Náftalì. Ó sì kó àwọn ènìyàn ní ìgbèkùn lọ sí Ásíríyà.
30 Nígbà náà, Hóséà ọmọ Álíyà, dìtẹ̀ sí Pékà ọmọ Remalíyà. Ó dojúkọ ọ́, ó sì pa á, ó sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba ní ogún ọdún Jótamù ọmọ Ùsáyà.
31 Fún ti ìyókù iṣẹ́ nígbà ìjọba Pékà, àti gbogbo ohun tí ó ṣe, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Ísírẹ́lì?
32 Ní ọdún keje Pékà ọmọ Remalíà ọba Ísírẹ́lì, Jótamù ọmọ Ùsáyà ọba Júdà bẹ̀rẹ̀ sí ní jọba.
33 Ó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n nígbà tí ó di ọba. Ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún mẹ́rìndínlógún. Orúkọ ìyá a rẹ̀ a máa jẹ́ Jérúṣà ọmọbìnrin Ṣádókù.
34 Ó ṣe ohun tí ó tọ́ lójú Olúwa gẹ́gẹ́ bí bàbá a rẹ̀ Ùsáyà ti ṣe.
35 Àwọn ibi gíga, bí ó ti wù kí ó rí, a kò sí wọn kúrò; Àwọn ènìyàn tẹ̀ṣíwájú láti rú ẹbọ àti láti sun tùràrí níbẹ̀: Jótamù tún ìlẹ̀kùn gíga tó ń kọ́ ní ti ilé tí a kọ́ fún Olúwa ṣe.
36 Fún ti ìyókù iṣẹ́ nígbà ìjọba Jótamù, àti ohun tí ó ṣe, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Júdà?
37 (Ní ayé ìgbà a nì, Olúwa bẹ̀rẹ̀ sí ní rán Résínì ọba Ṣíríà àti Pékà ọmọ Remálíà láti dojúkọ Júdà).
38 Jótamù sinmi pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀. A sì sin ín pẹ̀lú wọn ní ìlú ńlá Dáfídì, ìlú ńlá ti baba rẹ̀. Áhásì ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.