2 Ọba 4 BMY

Òróró Obìnrin Opó

1 Ìyàwó ọkùnrin kan láti ara ẹgbẹ́ wòlíì sunkún tọ Èlíṣà wá, “Ìránṣẹ́ rẹ ọkọ mi ti kú, ó sì mọ̀ wí pé ó bu ọlá fún Olúwa. Ṣùgbọ́n Nísinsìn yìí onígbèsè rẹ̀ ti ń bọ̀ láti wá kó ọmọ ọkùnrin mi gẹ́gẹ́ bí ẹrú rẹ̀.”

2 Èlíṣà dá a lóhùn pé, “Báwo ni èmi ṣe lè ràn ọ́ lọ́wọ́? Sọ fún mi; kí ni ìwọ ní ní ilé rẹ?”“Ìránṣẹ́ rẹ kò ní ohunkóhun níbẹ̀ rárá,” Ó wí pé, “àyàfi òróró kékeré.”

3 Èlíṣà wí pé, “Lọ yíká kí o sì béèrè lọ́wọ́ gbogbo àwọn aládùúgbò fún ìgò òfìfo. Má ṣe béèrè fún kékeré.

4 Nígbà náà, lọ sí inú ilé kí o sì pa lẹ̀kùn dé ní ẹ̀gbẹ́ ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin, dà òróró sínú gbogbo ìgò, gẹ́gẹ́ bí gbogbo rẹ̀ ti kún, kóo sí apákan.”

5 Ó sì fi sílẹ̀ lẹ́yìn náà ó ti ilẹ̀kùn ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ àti àwọn ọmọ rẹ̀. Wọ́n gbé ìgò wá fún un ó sì ń dà á.

6 Nígbà tí gbogbo ìgò náà kún, ó sọ fún ọmọ rẹ̀ pé, “Ẹ gbé òmíràn fún mi wá.”Ṣùgbọ́n wọ́n dáhùn pé, “Kò sí ìgò tí ó kù mọ́.” Nígbà náà ni òróró kò dà mọ́.

7 Ó sì lọ ó sì lọ sọ fún àwọn ènìyàn Ọlọ́run, ó sì wí pé, “Lọ, ta òróró náà kí o sì san gbésè rẹ. Ìwọ àti ọmọ rẹ kí ẹ máa sinmi lórí èyí tí ó kù.”

Ọmọ arábìnrin Kan Ará Ṣúnémù Jí Dìde Sáyé.

8 Ní ọjọ́ kan Èlíṣà lọ sí Ṣúnémù. Obìnrin ọlọ́rọ̀ kan sì wà níbẹ̀, ẹni tí ó rọ̀ ọ́ kí ó dúró jẹun. Bẹ́ẹ̀ ni nígbàkúgbà tí ó bá ń kọjá lọ, ó máa ń dúró níbẹ̀ láti jẹun.

9 Ó sọ fún ọkọ rẹ̀, “Mo mọ̀ pé ọkùnrin tí ó máa ń ṣábà wá sí ọ̀dọ̀ wa jẹ́ ọkùnrin mímọ́ Ọlọ́run.

10 Jẹ́ kí a ṣe yàrá kékeré kan sórí ilé kí a sì gbé ibùṣùn àti tábìlì oúnjẹ, àga kan àti àtùpà fún un. Nígbà náà ó lè dúró níbẹ̀ ní ìgbàkúgbà tí ó bá wá sọ́dọ̀ wa.”

11 Ní ọjọ́ kan nígbà tí Èlíṣà wá, ó lọ sí orí òkè ní yàrá rẹ̀ ó sì dùbúlẹ̀ síbẹ̀.

12 Ó sì wí fún ìránṣẹ́ rẹ̀ Géhásì pé, “Pe ará Ṣúnémù.” Bẹ́ẹ̀ ni ó sì pè é wá, ó sì dúró níwájú rẹ̀.

13 Èlíṣà wí fún un pé, “wí fún un, ‘Ìwọ ti lọ ṣe gbogbo àníyàn iṣẹ́ ìyìnrere fún wa. Nísinsìn yìí kí ni a lè ṣe fún ọ?’ ”“Ṣé alèjẹ́ agbẹnusọ fún ọ ní ọ̀dọ̀ ọba tàbí olórí ogun?”

14 “Kí ni a lè ṣe fún obìnrin yìí?” Èlíṣà béèrè.Géhásì wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, kò ní ọmọ, ọkọ rẹ̀ náà sì tún di arúgbó.”

15 Nígbà náà Èlíṣà wí pé, “Pè é,” Bẹ́ẹ̀ ni ó sì pè é, ó sì dúró ní àbáwọlé ẹnu ọ̀nà.

16 Èlíṣà sọ wí pé, “Ìwòyí ọdún tí ń bọ̀, ìwọ yóò fi ọwọ́ rẹ gbé ọmọ.”“Bẹ́ẹ̀ kọ́, Olúwa mi,” nkò fara mọ́ ọn. “Ma ṣe ṣi ìránṣẹ́ rẹ lọ́nà, ìwọ ènìyàn Ọlọ́run!”

17 Ṣùgbọ́n obìnrin náà lóyún ní ọdún kejì ní àkókò náà, ó bí ọmọ ọkùnrin kan, gẹ́gẹ́ bí Èlíṣà ti sọ fún un.

18 Ọmọ náà dàgbà, ní ọjọ́ kan, ó jáde lọ sí ọ̀dọ̀ bàbá rẹ̀, ó wà pẹ̀lú àwọn olùkórè.

19 “Orí mi!, Orí mi!” Ó wí fún baba rẹ̀.Baba rẹ̀ sọ fún ìránṣẹ́, “Gbé e lọ sọ́dọ̀ ìyá rẹ̀.”

20 Lẹ́yìn ìgbà tí ìránṣẹ́ náà ti gbé e sókè tí ó sì gbé e tọ ìyá rẹ̀ lọ, ọmọ ọkùnrin náà jókòó sórí ẹsẹ̀ rẹ̀ títí ó fi di ọ̀sán gangan, nígbà náà ó sì kú.

21 Ó lọ sí òkè ó sì tẹ́ ọmọ náà lórí ibùsùn ènìyàn Ọlọ́run, ó sì tilẹ̀kùn, ó jáde lọ.

22 Ó pe ọkọ rẹ̀ ó sì wí pé, “Jọ̀wọ́ rán ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan kí èmi kí ó lè lọ sí ọ̀dọ̀ ènìyàn Ọlọ́run kíákíá kí n sì padà.”

23 “Kí ni ó dé tí o fi fẹ́ lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ lónìí?” Ó béèrè. “Kì í ṣe oṣù túntún tàbí ọjọ́ ìsinmi.” ó wí pé“Gbogbo rẹ̀ ti dára”

24 Ó sì di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ní gàárì ó sì wí fún ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Má a nìṣó; má ṣe dẹsẹ̀ dúró dè mí àyàfi tí mo bá sọ fún ọ.”

25 Bẹ́ẹ̀ ni ó sì jáde wá, ó sì wá sọ́dọ̀ ènìyàn Ọlọ́run ní orí òkè Kámẹ́lì.Nígbà tí ó sì rí i láti òkèrè, ènìyàn Ọlọ́run sọ fún ìránṣẹ́ rẹ̀ Géhásì, “Wò ó! Ará Ṣúnémù nì!

26 Sáré lọ pàdé rẹ̀ kí o sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, ‘Ṣé o wà dáadáa? Ṣé ọkọ rẹ wà dáadáa? Ṣé ọmọ rẹ wà dáadáa?’ ”Ó wí pé, “Gbogbo nǹkan wà dáadáa.”

27 Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ ènìyàn Ọlọ́run ní orí òkè, ó gbá a ní ẹṣẹ̀ mú. Géhásì wá láti wá lé e dànù, ṣùgbọ́n ènìyàn Ọlọ́run wí pé, “Fi í sílẹ̀! Ó wà nínú ìpọ́njú, Kíkorò, ṣùgbọ́n Olúwa fi pamọ́ fún mi kò sì sọ ìdí rẹ̀ fún mi.”

28 “Ṣé mo béèrè ọmọ lọ́wọ́ rẹ, Olúwa mi?” Obìnrin náà wí pé, “Ṣé mi ò sọ fún ọ pe kí o, ‘Má ṣe fa ìrètí mi sókè’?”

29 Èlíṣà wí fún Géhásì pé, “Ká agbádá rẹ sínú ọ̀já àmùrè, mú ọ̀pá mi sí ọwọ́ rẹ kí o sì sáré. Tí o bá pàdé ẹnikẹ́ni má ṣe kí i, tí ẹnikẹ́ni bá kí ọ, má ṣe dá a lóhùn, fi ọ̀pá náà lé ojú ọmọ ọkùnrin náà.”

30 Ṣùgbọ́n ìyá ọmọ náà wí pé, “Gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti ń bẹ láàyè àti gẹ́gẹ́ bí ó ti wà láàyè, èmi kò níí fi ọ́ sílẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni ó sì dìde ó sì tẹ̀lé e.

31 Géhásì sì ń lọ síbẹ̀ ó sì fi ọ̀pá náà lé ojú ọmọ náà, ṣùgbọ́n kò sí ohùn dídún. Bẹ́ẹ̀ ni Géhásì padà lọ láti lọ bá Èlíṣà láti sọ fún un pé, “Ọmọ ọkùnrin náà kò tí ì dìde.”

32 Nígbà tí Èlíṣà dé inú ilé, níbẹ̀ ni òkú ọmọ ọkùnrin náà dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn.

33 Ó sì wọ ilé, ó sì ti ilẹ̀kùn mọ́ àwọn méjèèjì ó sì gbàdúrà sí Olúwa.

34 Nígbà náà ó dé orí ibùsùn, ó sùn sórí ọmọ ọkùnrin náà, ẹnu sí ẹnu, ojú sí ojú, ọwọ́ sí ọwọ́. Gẹ́gẹ́ bí ó ti nà ara rẹ̀ lórí rẹ̀, ara ọmọ náà sì gbóná.

35 Èlíṣà yípadà lọ, ó sì rìn padà ó sì jáde wá sínú ilé nígbà náà ó sì padà sí orí ibùsùn ó sì tún nà lé e ní ẹ̀ẹ̀kan sí i. Ọmọ ọkùnrin náà sì sín ní ìgbà méje ó sì sí ojú rẹ̀.

36 Èlíṣà sì pe Géhásì ó sì wí pé, “Pe ará Súnémù.” Ó sì ṣe bẹ́ẹ̀. Nígbà tí ó dé, ó wí pé, “Gba ọmọ rẹ.”

37 Ó sì wọlé, ó sì kúnlẹ̀ ṣíwájú ẹṣẹ̀ rẹ̀ ó sì tẹ̀ Orí sílẹ̀. Nígbà náà ó sì mú ọmọ rẹ̀ ó sì jáde lọ.

Ikú Nínú Ìkòkò

38 Èlíṣà padà sí Gílgálì ìyàn sì wà ní ilẹ̀ náà. Nígbà tí àwọn ọmọ wòlíì ṣe ìpàdé pẹ̀lú rẹ̀, ó sì wí fún ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Gbé ìkòkò ńlá ka iná kí o sì ṣe ọbẹ̀ aláta díẹ̀ fún àwọn ọkùnrin yìí.”

39 Ọ̀kan lára wọn jáde lọ sí orí pápá láti kó ewébẹ̀ jọ àti láti wá àjàrà ìgbẹ́. Ó sì kó díẹ̀ nínú ẹ̀fọ́ gbọ̀rọ̀ rẹ̀ jọ ó sì ka a kún aṣọ agbádá rẹ̀. Nígbà tí ó padà dé, ó sì gé wọn sínú ìkòkò ọbẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ẹni tí ó mọ ohun tí wọ́n ń jẹ.

40 Wọ́n da ọbẹ̀ náà jáde fun àwọn ọkùnrin náà, ṣùgbọ́n bí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí ní jẹ oúnjẹ náà, wọ́n sunkún jáde, “Ìwọ ènìyàn Ọlọ́run ikú ń bẹ nínú ìkòkò yìí!” Wọn kò sì le jẹẹ́.

41 Èlíṣà sì wí pé, “Mú ìyẹ̀fún díẹ̀ wá,” Ó sì fi sínú ìkòkò ó sì wí pé, “Kí ó sì fi fún àwọn ènìyàn láti jẹ.” Kò sì sí ohun tí ó léwu nínú ìkòkò náà.

42 Ọkùnrin kan wá láti Báálì-Ṣálíṣà, ó sì mú ogún ìṣù àkàrà bárílè, àkàrà tí wọ́n dín láti ara àkọ́kọ́ gbó àgbàdo, àti pẹ̀lú síírì ọkà tuntun. “Fún àwọn ènìyàn láti jẹ,” Èlíṣà wí pé

43 “Báwo ni èmi yóò ṣe gbé èyí ka iwájú àwọn ọgọ́ọ̀rún ènìyàn (100 men)?” Ìránṣẹ́ rẹ̀ béèrè.Ṣùgbọ́n Èlíṣà dá a lóhùn pé, “Gbé e fún àwọn ènìyàn láti jẹ, nítorí èyí ni ohun tí Olúwa sọ: ‘Wọn yóò jẹ yóò sì tún sẹ́kù’ ”

44 Nígbà náà ó gbé e ka iwájú wọn, wọ́n sì jẹ ẹ́, wọ́n sì ní èyí tó ṣẹ́kù, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25