1 Ní ọdún keje tí Jéhù, Jóásì di ọba, ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù fún ogójì ọdún. Orúkọ ìyá a rẹ̀ a máa jẹ́ Síbíyà: Ó wá láti Beeriṣébà.
2 Jóásì ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Olúwa ní gbogbo ọdún tí Jéhóíádà àlùfáà fi àsẹ fún un.
3 Àwọn ibi gíga, bí ó ti wù kí ó rí, a kò sí wọn ní ìdí; Àwọn ènìyàn sì tẹ̀ṣíwájú láti máa rú ẹbọ àti sísun tùràrí níbẹ̀.
4 Jóásì sọ fún àwọn àlùfáà pé, “Gba gbogbo owó tí wọ́n mú wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ mímọ́ sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa owó tí a gbà ní ìgbà kíka àwọn ènìyàn ìlú, owó tí a gbà láti ọwọ́ olúkúlùkù bí wọ́n ti ṣe jẹ́ ẹ̀yà àti owó tí ó ti ọkàn olúkúlùkù wá tí a múwá sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa.
5 Jẹ́ kí gbogbo àlùfáà gba owó náà lọ́wọ́ ọ̀kan nínú àwọn akápò. Kí a sì lò ó fún túntún ohunkóhun tí ó bá bàjẹ́ nínú ilé tí a kọ́ fún Olúwa ṣe.”
6 Ṣùgbọ́n ní ọdún kẹtàlélógún ọba Jóásì, àwọn àlùfáà kò ì tí ì tún ilé tí a kọ́ fún Olúwa ṣe.
7 Nígbà náà, ọba Jóásì pe Jéhóíádà àlùfáà àti àwọn àlùfáà yóòkù, ó sì bi wọ́n, pé “Kí ni ó dé tí ẹ̀yin kò fi tún ìbàjẹ́ tí a ṣe sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa ṣe? Ẹ má ṣe gba owó mọ́ lọ́wọ́ àwọn afowópamọ́, ṣùgbọ́n ẹ gbé e kalẹ̀ fún túntun ilé tí a kọ́ fún Olúwa ṣe.”
8 Àwọn àlùfáà faramọ́ pé wọn kò ní gba owó kankan mọ́ lọ́wọ́ àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ sì ni, wọn kò sì ní tún ilé tí a kọ́ fún Olúwa ṣe mọ́ fún ra wọn.
9 Jéhóíádà àlùfáà mú àpótí kan, ó sì lu ihò sí ìdérí rẹ̀. Ó gbé e sí ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ ní apá ọ̀tún bí ẹnìkan ti wọlé tí a kọ́ fún Olúwa. Àwọn àlùfáà tí ó ṣọ́ ẹnu ọ̀nà àbáwọlé fi sínú àpótí náà gbogbo owó tí a mú wá sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa.
10 Ìgbàkígbà tí wọ́n bá ti rí wí pé owó púpọ̀ wà nínú àpótí, akọ̀wé àti olórí àlùfáà yóò wá, wọ́n á ka owó náà tí wọ́n ti mú wá sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa. Wọn a sì kó o sínú àwọn àpò.
11 Nígbà tí wọ́n bá ti pinnu iye rẹ̀, wọn a kó owó náà fún àwọn tí a ti yàn láti bojútó iṣẹ́ náà lórí ilé tí a kọ́ fún Olúwa. Pẹ̀lú u rẹ̀, wọ́n sọ fún àwọn tí ó ń ṣiṣẹ́ lórí ilé tí a kọ́ fún Olúwa; Àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà àti àwọn olùkọ́lé.
12 Àwọn ilé ńlá àti àwọn agékúta. Wọ́n ra igi gẹdú àti òkúta tí wọ́n tọ́jú fún titun ilé tí a kọ́ fún Olúwa ṣe. Wọ́n tún ohun gbogbo tí wọ́n ná fún títún tẹ́ḿpílì ṣe.
13 Owó tí a mú wá sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa kò jẹ́ níná fún ṣíṣe òpó fàdákà, àlùmágàjí fìtílà, àwokòtò, ipè, ohun èlò wúrà tàbí ohun èlò fàdákà kan fún ilé tí a kọ́ fún Olúwa.
14 A sì san án fún àwọn ọkùnrin tí ó ń ṣiṣẹ́, tí wọ́n ń tọ́jú ilé tí a kọ́ fún Olúwa.
15 Wọn kò sì bá àwọn ọkùnrin náà sírò, ní ọwọ́ ẹni tí wọ́n fún ní owó láti san fún àwọn òṣìṣẹ́. Torí wọ́n ṣe é pẹ̀lú òdodo tí ó pé.
16 Owó láti ibi ọrẹ ẹ̀bi àti ọrẹ ẹ̀ṣẹ̀ ní a kò mú wá sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa: ó jẹ́ ti àwọn àlùfáà.
17 Ní déédéé àkókò yìí, Hásáélì ọba Ṣíríà gòkè lọ láti dojúkọ Gátì àti láti fi agbára mú un. Nígbà náà, ó yípadà láti dójukọ Jérúsálẹ́mù.
18 Ṣùgbọ́n Jóásì ọba Júdà mú gbogbo ohun mímọ́ tí a gbé ka iwájú tí a yà sọ́tọ̀ nípasẹ̀ baba rẹ̀—Jéhósáfátì, Jéhórámù àti Áhásáyà, àwọn ọba Júdà, àti àwọn ẹ̀bùn tí òun tìkálára rẹ̀ ti yà sọ́tọ̀ àti gbogbo wúrà, tí ó rí nínú ibi ìfowópamọ́ sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa àti níti ààfin ọba, ó sì fi wọ́n ránṣẹ́ sí Hásáélì; ọba Ṣíríà, tí ó sì fa padà kúrò ní Jérúsálẹ́mù.
19 Pẹ̀lú ìyókù ìṣe Jóásì, àti ohun gbogbo tí ó ṣe, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Júdà?
20 Àwọn oníṣẹ́ rẹ̀ dìtẹ̀ sí i wọ́n sì lù ú pa ní Bẹti-Mílò ní ọ̀nà sí Ṣílà.
21 Àwọn oníṣẹ́ tí ó pa á jẹ́ Jósábádì ọmọ Ṣíméátì àti Jéhósábádì ọmọ Ṣómérì. Ó kú, wọ́n sì sin-ín pẹ̀lú baba rẹ̀ ní ìlú ńlá ti Dáfídì. Ámásáyà ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.