2 Ọba 19 BMY

Àṣọtẹ́lẹ̀ Nípa Ìgbàlà Jérúsálẹ́mù.

1 Nígbà tí ọba Ẹṣkáyà gbọ́ èyí, ó fa aṣọ rẹ̀ ya ó sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀ ó sì lọ sí àgọ́ Olúwa

2 Ó sì rán Eliákímù olùtọ́jú ààfin, Ṣébínà akọ̀wé àti olórí àlùfáà gbogbo wọn sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀, sí ọ̀dọ̀ wòlíì Àìṣáyà ọmọ Ámósì.

3 Wọ́n sì sọ fún ún pé, “Èyí ni ohun tí Héṣékáyà sọ: ọjọ́ òní yí jẹ́ ọjọ́ ìpọ́njú àti ìbáwí àti ẹ̀gàn, gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí ọmọdé wá sí ojú ìbímọ tí kò sì sí agbára láti fi bí wọn.

4 Ó lè jẹ́ wí pé Olúwa Ọlọ́run yóò gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ olùdarí pápá, ẹni tí ọ̀gá rẹ̀, ọba Ásíríà, ti rán láti fi Ọlọ́run alààyè sẹ̀sín, yóò sì báa wí fún ọ̀rọ̀ ti Olúwa Ọlọ́run rẹ ti gbọ́. Nítorí náà gbàdúrà fún ìyókù àwọn tí ó wà láàyè.”

5 Nígbà tí ìránṣẹ́ ọba Héṣékáyà lọ sí ọ̀dọ̀ Àìṣáyà,

6 Àìṣáyà wí fún wọn pé, “Sọ fún ọ̀gá rẹ, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa sọ pé: Ẹ má ṣe bẹ̀rù ohun tí ẹ̀yin ti gbọ́—àwọn ọ̀rọ̀ ìhàlẹ̀ pẹ̀lú èyí ti ọba Áṣíríà ti sọ̀rọ̀ òdì sí mi.

7 Gbọ́! Èmi yóò rán ẹ̀mí kan sínú rẹ̀ nígbà tí ó bá sì gbọ́ ariwo, yóò sì padà sí ìlú rẹ̀, níbẹ̀ ni èmi yóò sì gbé gée lulẹ̀ pẹ̀lú idà.’ ”

8 Nígbà tí olùdarí pápá gbọ́ wí pé ọba Áṣíríà ti kúrò lákìsì ó sì padà ó sì rí ọba níbi ti ó gbé ń bá Líbíńà jà.

9 Nísinsìn yìí Ṣenakéríbù sì gbọ́ ìròyìn wí pé Tíránákà, ọba Etiópíà ti Éjíbítì wá ó sì ń yan jáde lọ láti lọ bá a jagun. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì tún rán onísẹ́ sí Héṣékíáyà pẹ̀lú ọ̀rọ̀ yìí pé:

10 “Sọ fún Héṣékíáyà ọba Júdà pé: Má ṣe jẹ́ kí òrìṣà tí o gbékalẹ̀ kí ó tàn ó jẹ nígbà tí ó wí pé, ‘Jérúsálẹ́mù a kò ní fi lé ọwọ́ ọba Ásíríà.’

11 Lọ́ọ̀tọ́ ìwọ ti gbọ́ gbogbo ohun tí ọba Ásíríà tí ó ṣe sí gbogbo àwọn ìlú, ó pa wọ́n run pátapáta. Ìwọ yóò sì gbàlà?

12 Ṣé àwọn òrìṣà orílẹ̀ èdè tí a ti parun láti ọ̀dọ̀ àwọn babańlá mi gbà wọ́n là: òrìṣà Gósánì, Háránì Réṣéfù àti gbogbo ènìyàn Édẹ́nì tí wọ́n wà ní Télásárì?

13 Níbo ni ọba Hámátì wa, ọba Árípádì, ọba ìlú Séfárífáímù, ti Hénà, tàbí ti Ífà gbé wà?”

Àdúrà Heṣekíàyà

14 Heṣekíàyà gba lẹ́tà láti ọ̀dọ̀ ìránṣẹ́ ó sì kà á. Nígbà náà ó sì lọ sí òkè ilé tí a kọ́ fún Olúwa ó sì tẹ́ ẹ ṣíwájú Olúwa.

15 Heṣekáyà gbàdúrà sí Olúwa: “Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì, tí ń gbé ní àárin àwọn kérúbù, ìwọ nìkan ni Ọlọ́run lórí gbogbo ìjọba tí ó wà láyé, ìwọ ti dá ọ̀run àti ayé.

16 Dẹtí sílẹ̀, Olúwa kí o sì gbọ́; la ojú ù rẹ, Olúwa, kí o sì rí i, gbọ́ ọ̀rọ̀ Ṣenakérúbù tí ó rán láti fi bú Ọlọ́run alààyè.

17 “Òtítọ́ ni, Olúwa, wí pé ọba Ásíríà ti pa orílẹ̀ èdè wọ̀nyìí run àti ilẹ̀ wọn.

18 Wọ́n ti ju òrìṣà wọn sínú iná wọn sì ti bà wọ́n jẹ́, nítorí pé wọn kì í ṣe Olúwa. Ṣùgbọ́n, wọ́n jẹ́ igi àti òkúta tí a ṣe lọ́ṣọ̀ ọ́ pẹ̀lú ọwọ́ ènìyàn.

19 Nísinsìn yìí Olúwa Ọlọ́run wa, gbà wá kúrò lọ́wọ́ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àwọn ìjọba lórí ilẹ̀ ayé le mọ̀ pé ìwọ nìkanṣoṣo ni, Olúwa Ọlọ́run wa.”

Àìṣáyà Sọtẹ́lẹ̀ Nípa Ìṣubú Ṣenakérúbù.

20 Nígbà náà Àìṣáyà ọmọ Ámósì rán oníṣẹ́ sí Heṣekíàyà pé: “Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ: Mo ti gbọ́ àdúrà rẹ nípa ti Ṣenakérúbù ọba Ásíríà.

21 Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa ti sọ nípa rẹ̀:“ ‘Wúndíá ọmọbìnrin Ṣíónìkẹ́gàn rẹ ó sì fi ọ́ ṣe ẹlẹ́yà.Ọmọbìnrin Jérúsálẹ́mùmi orí sí ọ gẹ́gẹ́ bí o ti sálọ.

22 Ta ni ìwọ ti bú tí o sì kẹ́gàn rẹ̀?Lórí ta ni ìwọ ti gbé gbé ohùn rẹsókè tí ó sì gbé ojú sókè sí ọ ní ìgbéraga?Lórí ẹni mímọ́ ti Ísírẹ́lì!

23 Nípa àwọn ìránṣẹ́ rẹÌwọ ti ṣe ìkójọpọ̀ èébú sí Olúwa.Ìwọ sì ti sọ pé,“Pẹ̀lú ọ̀pọ̀ kẹ̀kẹ́ miÈmi sì ti fi dé orí àwọn òkè ńlá,ibi gíga jùlọ ní LébánónìMo sì ti gé igi gíga jùlọ kédárìlulẹ̀, àti àyò igi fírì rẹ̀.Mo ti dé ibi orí òkè ìbùwọ́ ẹ̀gbẹ́ kanibi tí ó dára jù nínú igbó rẹ.

24 Mo ti gbẹ́ kàǹga ní ilẹ̀ àjèjìMo sì mu omi níbẹ̀.Pẹ̀lú àtẹ́lẹṣẹ̀ mi,Èmi ti gbẹ́ gbogbo omi odò tí ó wà ní Éjíbítì.”

25 “ ‘Ṣé ìwọ kò tí ì gbọ́?Ní ọjọ́ pípẹ́ sẹ́yìn mo yàn án.Ní ọjọ́ ogbó ni mo ṣètò rẹ̀;nísinsìn yìí mo ti mú wá sí ìkọjápé ìwọ ti yí ìlú olódi padà díòkítì àlàpà òkúta.

26 Àwọn ènìyàn wọn ń gbẹ nípa,wọ́n ti dàá láàmúwọ́n sì ti sọọ́ di ìtìjú.Wọ́n dà bí koríko ìgbẹ́ lórí pápá,gẹ́gẹ́ bí ọkà tí ó rẹ̀ dànù kí ó tó dàgbà sókè,gẹ́gẹ́ bí fífún ọkà tí ó hù jáde.

27 “ ‘Ṣùgbọ́n èmi mọ ibi tí ìwọdúró àti ìgbà tí ìwọ bá dé tàbílọ àti bí ìwọ ṣe ikáanú rẹ: sí mi.

28 Ṣùgbọ́n ikáanú rẹ sí mi àti ìrora rẹ dé etí mi,Èmi yóò gbé ìwọ̀ mi sí imúrẹ àti ìjánú mi sí ẹnu rẹ,èmi yóò mú ọ padà nípa wíwá rẹ’

29 “Èyí yóò jẹ́ àmìn fún ọ, ìwọ Heṣekíàyà:“Ọdún yìí ìwọ yóò jẹ ohun tí ó bá hù fún rara rẹ̀,àti ní ọdún kejì ohun tí ó bá hù jáde láti inú iyẹn.Ṣùgbọ́n ní ọdún kẹta, gbìn kí o sì kórè,gbin ọgbà àjàrà kí o sì jẹ èṣo rẹ̀.

30 Lẹ́ẹ̀kan sí i ìyókù ti ilé Júdàyóò sì tún hu gbòǹgbòlábẹ́, yóò sì so èṣo lókè.

31 Láti inú Jérúsálẹ́mù ní àwọn ìyókù yóò ti wáàti láti orí òkè Ṣíónì ni ọ̀pọ̀ àwọn tí ó ṣá àsálà.Ìtara Olúwa àwọn ọmọ ogun yóò ṣe èyí.

32 “Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa ṣọ nípa ti ọba Áṣíríà:“Kò ní wọ ìlú yìítàbí ta ọfà síbí.Kò ní wá níwájú rẹ pẹ̀lúàpáta tàbí kó ìdọ̀tí àgbò sí ọ̀kánkán rẹ.

33 Nípa ọ̀nà tí ó gbà wá niyóò padà; kì yóò wọ ìlú ńlá yìí,ni Olúwa wí.

34 Èmi yóò dá ààbò bo ìlú ńlá yìí,èmi yóò sì paámọ́ fún èmi tìkálára mi àti fún Dáfídì ìránṣẹ́ mi.”

35 Ní alẹ́ ọjọ́ náà, ańgẹ́lì Olúwa jáde lọ ó sì pa ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ènìyàn ní ibùdó àwọn ará Aṣíríà. Nígbà tí wọ́n sì dìde dúró ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì níbẹ̀ ni gbogbo òkú wà!

36 Bẹ́ẹ̀ ni Ṣenakérúbù ọba Áṣíríà wọ àgọ́ ó sì padà, ó sì padà sí Nínéfè ó sì dúró níbẹ̀.

37 Ní ọjọ́ kan, nígbà tí ó sùn nínú ilé òrìṣà Nísírókù, ọmọkùnrin rẹ̀ Adiramélékì àti Ṣárésérì gé e lulẹ̀ pẹ̀lú idà, wọ́n sì sálọ sí ilẹ̀ Árárátì Ésáráhádónì ọmọkùnrin rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25