2 Ọba 10 BMY

A Pa Ìdílé Áhábù.

1 Nísinsìn yìí, Áhábù sì ní àádọ́rin ọmọkùnrin ní ìdílé rẹ̀ ní Ṣamáríà. Bẹ́ẹ̀ ni, Jéhù kọ lẹ́tà, ó sì fi wọ́n ránṣẹ́ sí Samáríà: sí àwọn oníṣẹ́ Jésérẹ́lì, sí àwọn àgbààgbà àti sí àwọn olùtọ́jú àwọn ọmọ Áhábù. Ó wí pé,

2 “Ní kété tí lẹ́tà bá ti dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, níwọ̀n ìgbà tí àwọn ọmọ ọ̀gá a rẹ wà pẹ̀lú rẹ, ìwọ sì ní àwọn kẹ̀kẹ́ àti àwọn ẹṣin, ìlú olódi kan pẹ̀lú ohun ìjà,

3 yan èyí tí ó dára àti èyí tí ó níye jùlọ nínú àwọn ọmọkùnrin ọ̀gá à rẹ, kí o sì gbé e lé orí ilé baba a rẹ̀. Nígbà náà, kí o sì jà fún, ilé ọ̀gá à rẹ.”

4 Ṣùgbọ́n dẹ́rùbà wọ́n, wọ́n sì wí pé, “Tí ọba méjì kò bá le kojú ìjà sí i, báwo ni a ṣẹ le è ṣeé?”

5 Bẹ́ẹ̀ ni olùpínfúnni a fún, olórí ìlú ńlá, àwọn àgbààgbà àti àwọn olùtọ́jú náà rán iṣẹ́ yìí sí Jéhù: “Ìránṣẹ́ rẹ ni àwa jẹ́ pẹ̀lú, àwa yóò ṣe ohunkóhun tí o bá sọ. Àwa kì yóò yan ẹnikẹ́ni gẹ́gẹ́ bí ọba; Ìwọ ṣe ohunkóhun tí o rò pé ó dára jù.”

6 Nígbà náà, Jéhù kọ lẹ́tà kejì síwọn, wí pé, “Tí ìwọ bá wà ní ìhà tèmi, tí o sì pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, mú orí àwọn ọmọkùnrin ọ̀gá à rẹ wá sí ọ̀dọ̀ mi ní Jésérẹ́lì ní ìwòyí ọ̀la.”Nísinsìn yìí, àwọn ọmọ aládé bìnrin ti ọba, àádọ́rin wọn sì wà pẹ̀lú àwọn adarí ọkùnrin ní ìlú àwọn tí wọ́n ń bọ́ wọn.

7 Nígbà tí ìwé náà dé àwọn ọkùnrin wọ̀nyí mú gbogbo àwọn ọmọ aládé bìnrin, wọ́n sì pa gbogbo àádọ́rin wọn. Wọ́n gbé orí i wọn sí inú apẹ̀rẹ̀, wọ́n fi ránṣẹ́ sí Jéhù ní Jésérẹ́lì.

8 Nígbà tí ìránṣẹ́ náà dé, ó sọ fún Jéhù, “Wọ́n ti gbé orí àwọn ọmọ aládé bìnrin náà wá.”Nígbà náà Jéhù pàṣẹ, “Kó wọn sí ẹ̀bú méjì sí àbáwọlé ìlẹ̀kùn ìlú ńlá títí di òwúrọ̀.”

9 Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, Jéhù jáde lọ. Ó dúró níwájú gbogbo àwọn ènìyàn, ó sì wí pé, “Ẹ̀yin jẹ́ aláìjẹ̀bi. Èmi ni mo dìtẹ̀ sí ọ̀gá mi, tí mo sì pa á, ṣùgbọ́n ta ni ó pa gbogbo àwọn wọ̀nyí!?

10 Nígbà yìí, kò sí ọ̀rọ̀ kan tí Olúwa ti sọ sí ilé Áhábù tí yóò kùnà. Olúwa ti ṣe ohun tí ó ṣèlérí nípaṣẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀ Èlíjà.”

11 Bẹ́ẹ̀ ni Jéhù pa gbogbo ẹni tí ó kù ní ilé Áhábù, pẹ̀lú pẹ̀lú gbogbo àwọn ọkùnrin ìjòyè rẹ̀, àwọn ọ̀rẹ́ ẹ rẹ̀ tímọ́-tímọ́ àti àwọn àlùfáà rẹ̀, láì ku ẹni tí ó yọ nínú ewu fún un.

12 Jéhù jáde lọ, ó sì lọ sí ọ̀kánkán Ṣamáríà. Ní Bẹti-Ékédì tí àwọn olùṣọ́ àgùntàn.

13 Ó pàdé díẹ̀ lára àwọn ìbátan Áhásáyà ọba Júdà, ó sì béèrè, “Ta ni ẹ̀yin ń ṣe?”Wọ́n wí pé, “Àwa jẹ́ ìbátan Áhásáyà, àwa sì ti wá láti kí ìdílé ọba àti ti mọ̀mọ́ ayaba.”

14 “Mú wọn láàyè!” ó pàṣẹ. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n mú wọn láàyè, wọ́n sì pa wọ́n ní ẹ̀bá kọ̀nga Bẹti-Ékédì, ọkùnrin méjìlélógójì. Kò sì fi ẹnìkan sílẹ̀ láìkù.

15 Lẹ́yìn ìgbà tí ó kúrò níbẹ̀, ó wá sórí Jéhónádábù ọmọ Rékábù tí ó wà ní ọ̀nà rẹ̀ láti lọ bá a. Jéhù kí i, ó sì wí pé, “Ṣé ìwọ wà ní ìbárẹ́ pẹ̀lú mi, bí èmi ti wa pẹ̀lú ù rẹ?”“Èmi wà,” Jéhónádábù dáhùn.“Bí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀,” Jéhù wí, “fún mi ní ọwọ́ ọ̀ rẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe pẹ̀lú, Jéhù sì ràn án ọ́ lọ́wọ́ sókè sí inú kẹ̀kẹ́.

16 Jéhù wí pé, “Wá pẹ̀lú ù mi; kí o sì rí ìtara mi fún Olúwa.” Nígbà náà ó jẹ́ kí ó gun kẹ̀kẹ́ rẹ̀.

17 Nígbà tí Jéhù wá sí Ṣamáríà, ó pa gbogbo àwọn tí a fi kalẹ̀ ní ìdílé Áhábù; ó pa wọ́n run, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa tí a sọ sí Èlíjà.

A Pa Gbogbo Àwọn Òjíṣẹ́ Báálì

18 Nígbà náà, Jéhù kó gbogbo àwọn ènìyàn jọ, ó sì wí fún wọn pé, “Áhábù sin Báálì díẹ̀; ṣùgbọ́n Jéhù yóò sìn ín púpọ̀.

19 Nísinsìn yìí, ẹ pe gbogbo àwọn wòlíì Báálì jọ, gbogbo àwọn òjíṣẹ́ rẹ̀ àti gbogbo àlùfáà rẹ̀. Rí i wí pé, kò sí nǹkankan tí ó ń sọnù nítorí ẹ̀mi yóò rú ẹbọ ńlá fún Báálì. Ẹnìkíní tí ó bá kọ̀ láti wá, kò ní wà láàyè mọ́.” Ṣùgbọ́n Jéhù fi ẹ̀tàn ṣe é, kí ó lè pa àwọn òjíṣẹ́ Báálì run.

20 Jéhù wí pé, “ẹ pe àpẹ̀jọ ní wòyí ọ̀la fún Báálì.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kéde rẹ.

21 Nígbà náà, ó rán ọ̀rọ̀ káàkiri Ísírẹ́lì, gbogbo àwọn òjíṣẹ́ Báálì sì wá: kò sí ẹnìkan tí ó dúró lẹ́yìn. Wọ́n kún ilé tí a kọ́ fún òrìṣà títí tí ó fi kún láti ìkángun èkíní títí dé èkejì.

22 Jéhù sì sọ fún olùṣọ́ pé, “Kí ó mú aṣọ ìgúnwà wá fún gbogbo àwọn òjíṣẹ́ Báálì.” Bẹ́ẹ̀ ni ó mú aṣọ ìgúnwà jáde wá fún wọn.

23 Nígbà náà, Jéhù àti Jéhónádábù ọmọ Rékábù lọ sí inú ilé tí a kọ́ fún òrìṣà Báálì. Jéhù sì wí fún àwọn òjíṣẹ́ Báálì pé, “Wò ó yíká, kí o sì rí i pé kò sí ìránṣẹ́ Ọlọ́run kankan pẹ̀lú yín níbí—kìkì òjíṣẹ́ Báálì.”

24 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n wọ inú ilé lọ láti lọ rú ẹbọ àti ọrẹ sísun. Nísinsìn yìí Jéhù ti rán ọgọ́rin ọkùnrin sí ìta pẹ̀lú ìkìlọ̀ yìí: “Tí ẹnikẹ́ni nínú yín bá jẹ́ kí ẹnikẹ́ni nínú àwọn ọkùnrin tí mo ń gbé sí ọwọ́ yín ó sá lọ, yóò jẹ́ ẹ̀mí yín fún ẹ̀mí ì rẹ.”

25 Ní kété tí Jéhù ti parí ṣíṣe ọrẹ sísun, ó pàṣẹ fún àwọn olùṣọ́ àti àwọn ìjòyè: “Wọlé lọ, kí o sì pa wọ́n; Má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni kí ó sálọ.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gé wọn lulẹ̀ pẹ̀lú idà. Àwọn olùṣọ́ àti ìjòyè ju ara wọn síta, wọ́n sì wọ inú ojúbọ ti ilé tí a kọ́ fún òrìṣà Báálì.

26 Wọ́n gbé òkúta bíbọ náà jáde láti inú ilé tí a kọ́ fún òrìṣà Báálì, wọ́n sì jó o.

27 Wọ́n fọ́ òkúta bíbọ ti Báálì náà túútúú, wọ́n sì ya ilé òrìṣà Báálì bolẹ̀. Àwọn ènìyàn sì ń lò ó fún ilé ìgbẹ́ títí di ọjọ́ òní.

28 Bẹ́ẹ̀ ni Jéhù pa sísin Báálì run ní Ísírẹ́lì.

29 Bí ó ti wù kí ó rí, kò yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jéróbóámù ọmọ Nébátì, tí ó ṣokùnfà Ísírẹ́lì láti dá—ti sísin ẹgbọ̀rọ̀ màlúù wúrà ní Bétélì àti Dánì.

30 Olúwa sì sọ fún Jéhù pé, “Nítorí ìwọ ti ṣe dáradára ní ṣíṣe èyí tí ó tọ́ ní ojú mi, tí o sì ti ṣe sí ilé Áhábù gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí ó wà ní ọkàn mi, àwọn ọmọ ọ̀ rẹ yóò jókòó lórí ìtẹ́ Ísírẹ́lì títí dé ìran kẹrin.”

31 Ṣíbẹ̀ Jéhù kò ṣe pẹ̀lẹ́ láti pa òfin Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì mọ́ pẹ̀lú tọkàntọkàn. Òun kò yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jéróbóámù èyí tí ó ṣokùnfà Ísírẹ́lì láti dá.

32 Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, Olúwa ti bẹ̀rẹ̀ sí ní dín iye Ísírẹ́lì kù. Hásáélì fi agbára tẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní gbogbo agbégbé wọn.

33 Ìlà-oòrùn ti Jọ́dánì ni gbogbo ilẹ̀ ti Gílíádì (ẹ̀kún ilẹ̀ ti Gádì, Rúbẹ́nì, àti Mánásè) láti Áróérì, tí ó wà létí Ánónì Gọ́ọ́jì láti ìhà Gílíádì sí Básánì.

34 Fún ti òmìíràn ti iṣẹ́ ìjọba Jéhù, gbogbo ohun tí ó ṣe, gbogbo àṣeyọrí rẹ̀, ṣé a kò kọ wọ́n sí inú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Ísírẹ́lì?

35 Jéhù sin mi pẹ̀lú baba a rẹ̀, a sì sin ín sí Ṣamáríà Jéhóáhásì ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.

36 Àkókò tí Jéhù fi jọba lórí Ísírẹ́lì ní Ṣamáríà jẹ́ ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25