2 Ọba 13 BMY

Jéhóáhásì Ọba Ísírẹ́lì

1 Ní ọdún kẹtàlélógún ti Jóásì ọmọ ọba Áhásáyà ti Júdà, Jéhóáhásì ọmọ Jéhù di ọba Ísírẹ́lì ní Ṣamáríà. Ó sì jọba fún ọdún mẹ́tadínlógún.

2 Ó ṣe búburú níwájú Olúwa nípa títẹ̀lé ẹ̀ṣẹ̀ Jéróbóámù ọmọ Nébátì, èyí tí ó ti fa Ísírẹ́lì láti dá, kò sì yípadà kúrò nínú wọn.

3 Bẹ́ẹ̀ ni ìbínú Olúwa ru sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àti fún ìgbà pípẹ́, ó fi wọ́n pamọ́ sí abẹ́ agbára ọba Hásáélì ọba Ṣíríà àti Bẹni-Hádádì ọmọ rẹ̀.

4 Nígbà náà Jéhóáhásì kígbe ó wá ojú rere Olúwa, Olúwa sì tẹ́tí sí i. Nítorí ó rí bí ọba Ṣíríà ti ń ni Ísírẹ́lì lára gidigidi.

5 Olúwa pèsè Olùgbàlà fún Ísírẹ́lì, wọ́n sì sá kúrò lọ́wọ́ agbára Ṣíríà. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbé nínú ilé ara wọn gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti wà tẹ́lẹ̀.

6 Ṣùgbọ́n wọn kò yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ ilé Jéróbóámù, èyí tí ó ti fa Ísírẹ́lì láti dá. Wọ́n tẹ̀ṣíwájú nínú rẹ̀ pẹ̀lú òpó Áṣérà dúró síbẹ̀ ní Ṣamáríà.

7 Kò sí ohùn kan tí wọ́n fi sílẹ̀ ní ti ọmọ ogun Jéhóáhásì àyàfi àádọ́ta ọkùnrin ẹlẹ́ṣin, kẹ̀kẹ́ mẹ́wàá, àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ọmọ ogun ẹlẹ́sẹ̀, nítorí ọba Ṣíríà ti pa ìyókù run, ó sì ṣe wọ́n bí eruku nígbà pípa ọkà.

8 Fún ti ìyókù ìṣe Jéhóáhásì fún ìgbà, tí ó fi jọba, gbogbo ohun tí ó ṣe àti àṣeyọrí rẹ̀ ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Ísírẹ́lì?

9 Jéhóáhásì sinmi pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀. A sì sin ín sí Samáríà, Jéhóásì ọmọ rẹ̀ sì rọ́pọ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.

10 Ní ọdún kẹtàdínlógójì tí Jóásì ọba Júdà, Jéhóásì ọmọ Jéhóáhásì di ọba Ísírẹ́lì ní Ṣamáríà ó sì jọba fún ọdún mẹ́rìndínlógún.

11 Ó ṣe búburú ní ojú Olúwa, kò sì yípadà kúrò nínú ọ̀kankan nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jéróbóámù ọmọ Nébátì èyí tí ó ti ti Ísírẹ́lì láti fà. Ó sì tẹ̀síwájú nínú wọn.

12 Fún ti ìyókù iṣẹ́ Jéhóásì fún ìgbà tí ó fi jọba, gbogbo ohun tí ó ṣe, pẹ̀lú àṣeyọrí rẹ̀ pẹ̀lú ogun rẹ̀ sí Ámásáyà ọba Júdà, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Ísírẹ́lì?

13 Jéhóásì sinmi pẹ̀lú àwọn baba a rẹ̀. Jéróbóámù sì rọ́pò rẹ̀ lórí ìtẹ́. A sin Jéhóásì sí Samáríà pẹ̀lú àwọn ọba Ísírẹ́lì.

14 Nísinsìn yìí, Èlíṣà ń jìyà lọ́wọ́ àìsàn, lọ́wọ́ èyí tí ó sì kú. Jéhóásì ọba Ísírẹ́lì lọ láti lọ wò ó, ó sì ṣunkún lórí rẹ̀. “Baba mi!, Baba mi!” Ó ṣunkún. “Àwọn kẹ̀kẹ́ àti àwọn ọkùnrin ẹlẹ́ṣin Ísírẹ́lì.!”

15 Èlíṣà wí pé, “Mú ọrun kan àti àwọn ọfà,” ó sì ṣe bẹ́ẹ̀.

16 “Mú ọrun ní ọwọ́ rẹ.” Ó wí fún ọba Ísírẹ́lì. Nígbà tí ó ti mú u, Èlíṣà mú ọwọ́ rẹ̀ lé ọwọ́ ọba.

17 “Ṣí fèrèsé apá ìlà oòrùn,” ó wí, pẹ̀lú ó sì ṣéé: “Ta á!” Èlíṣà wí, ó sì ta á. “Ọfà ìṣẹ́gun Olúwa; ọfà ìṣẹ́gun lórí Ṣíríà!” Èlíṣà kéde. “Ìwọ yóò pa àwọn ará Ṣíríà run pátapáta ní Áfékì.”

18 Nígbà náà ó wí pé, “Mú àwọn ọfà náà,” ọba sì mú wọn. Èlíṣà wí fún un pé, “Lu ilẹ̀.” Ó lù ú lẹ́ẹ̀mẹ́ta, ó sì dáwọ́ dúró.

19 Ènìyàn Ọlọ́run sì bínú sí i, ó sì wí pé, “Ìwọ kò bá ti lu ilẹ̀ ní ẹẹ̀marùn-ún tàbí ní ẹ̀ẹ̀mẹfà; Nígbà náà, ìwọ kò bá ti ṣẹ́gun Ṣíríà àti pa á run pátapáta ṣùgbọ́n Nísinsìn yìí ìwọ yóò ṣẹ́gun rẹ̀ ní ẹ̀mẹ́ta péré.”

20 Èlíṣà kú a sì sin ín.Ẹgbẹ́ Àwọn ará Móábù máa ń wọ orílẹ̀ èdè ní gbogbo àmọ́dún.

21 Bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kan ti ń sin òkú ọkùnrin kan, lójijì wọ́n rí ẹgbẹ́ àwọn oníjadì: Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ju òkú ọkùnrin náà sínú ibojì Èlíṣà. Nígbà tí ara ọkùnrin náà kan egungun Èlíṣà, ó padà wá sí ayé, ó sì dúró ní ẹsẹ̀ rẹ̀.

22 Hásáélì ọba Ṣíríà ni Ísírẹ́lì lára ní gbogbo àkókò tí Jéhóáhásì fi jọba.

23 Ṣùgbọ́n Olúwa ṣàánú fún wọn ó sì ní ìyọ́nú, ó sì fiyèsí wọn nítorí májẹ̀mú rẹ̀ pẹ̀lú Ábúráhámù, Ísákì àti Jákọ́bù. Títí di ọjọ́ òní, kì í ṣe ìfẹ́ inú rẹ̀ láti pa wọ́n run tàbí lé wọn lọ níwájú rẹ̀.

24 Hásáélì ọba Ṣíríà kú, Bẹni-Hádádì ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.

25 Nígbà náà, Jéhóásì ọmọ Jéhóáhásì gbà padà kúrò lọ́wọ́ Bẹni-Hádádì ọmọ Hásáélì àwọn ìlú tí ó ti gbà nínú ogun látọ̀dọ̀ baba rẹ̀ Jéhóáhásì. Ní ẹ̀ẹ̀mẹ́ta, Jéhóásì ṣẹ́gun rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó gba ìlú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì padà.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25