1 Kíróníkà 12 BMY

Àwọn Ọ̀gágun Tí Ó Dúró Ti Dáfídì

1 Àwọn wọ̀nyí ni ọkùnrin tí ó wá sí ọ̀dọ̀ Dáfídì ní Ṣíkílágì Nígbà tí ó sá kúrò níwájú Ṣọ́ọ̀lù ọmọ Kísì (Wọ́n wà lára àwọn jagunjagun ẹni tí ó ràn-án lọ́wọ́ láti ibi ìjà;

2 Wọ́n sì mú wọn pẹ̀lú ìtẹríba wọ́n sì lágbára láti ta ọfà tàbí láti ta kànnàkànnà òkúta ní ọwọ́ òsì tàbí ní ọwọ́ ọ̀tún, wọ́n sì jẹ́ ìbátan ọkùnrin Ṣọ́ọ̀lù láti ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì):

3 Áhíésérì Olórí wọn àti Jóáṣì àwọn ọmọ Ṣémà ará Gíbéà: Jésíélì àti pélétì ọmọ Ásímáfétì, Bérákà, Jéhù ará Ánátótì.

4 Àti Íṣímáyà ará Gíbíónì, ọkùnrin alágbára kan lára àwọn ọgbọ̀n ẹni tí ó jẹ́ olórí nínú àwọn ọgbọ̀n; Jeremáyà, Jáhásíélì, Jóhánánì, Jósábádì ará Gédérà,

5 Élúsáì, Jérímótì, Béálíà, Ṣémáríà àti Ṣéfátíyà ará Hárófì;

6 Élíkánà, Íṣái, Ásárélì, Jóésérì àti Jáṣóbéà ará kórà;

7 Àti Jóélà, àti Ṣébádíà àwọn ọmọ Jéróhámù láti Gédárì.

8 Díẹ̀ lára àwọn ará Gádì yà sọ́dọ̀ Dáfídì ní ibi gíga ní ihà. Wọ́n sì jẹ́ onígboyà ológun tí ó múra fún ogun tí ó sì lágbára láti di àṣà àti ẹsin mú. Ojú wọn sì dàbí ojú kìnìún, wọ́n sì yára bí àgbọ̀nrín lórí àwọn òkè.

9 Ésérì sì jẹ́ ìjòyè,Ọbádáyà sì jẹ́ igbékejì akọgun, Élíábù ẹlẹ́kẹ́ta,

10 Míṣimánà ẹlẹ́kẹ́rin, Jeremíà ẹlẹ́ẹ̀kárùn-ún

11 Átaì ẹlẹ́kẹ́fà, Ẹlíélì èkéje,

12 Jóhánánì ẹlẹ́kẹ́jọ Élísábádì ẹlẹ́ẹ̀kẹ́sàn-án

13 Jeremíàh ẹlẹ́kẹ́wàá àti Mákíbánáì ẹlẹ́kọ́kànlá.

14 Àwọn ará Gádì wọ́n sì jẹ́ olórí ogun; ẹni tí ó kéré jù sì jẹ́ àpapọ̀ ọgọ́rùn-ún, àti fún ẹni tí ó pọ̀jù fún ẹgbẹ̀rún.

15 Àwọn ni ẹni tí ó rékọjá Jọ́dánì ní oṣù àkọ́kọ́ nígbà tí ó kún bo gbogbo bèbè Rẹ̀, wọ́n sì lé gbogbo àwọn tí ó ń gbé nínú àfonífojì, lọ sí ìlà oòrùn àti níhà ìwọ̀ oòrùn.

16 Ìyòókù ará Bẹ́ńjámínì àti àwọn díẹ̀ ọkùnrin láti Júdà lọ sí ọ̀dọ̀ Dáfídì ní ibi gíga.

17 Dáfídì sì lọ láti lọ pàdé wọn ó sì wí fún wọn pé, “Tí ẹ bá wá sọ́dọ̀ mi lálàáfíà, láti ràn mí lọ́wọ́ mo sẹtan láti mú un yín wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú mi ṣùgbọ́n tí ẹ bá wá láti dá mi sí fún àwọn ọ̀ta mi nígbà tí ọwọ́ mi bá mọ́ kúrò nínú ìwà agbára, kí Ọlọ́run àwọn baba wa kí ó sì ri kí ó sì ṣe ìdájọ́.”

18 Nígbà náà Ẹ̀mí Mímọ́ wa sórí Ámásáyà ìjòyè àwọn ọgbọ̀n, ó sì wí pé:“Tìrẹ ni àwa ń se, ìwọ Dáfídì!Àwa pẹ̀lú rẹ, ìwọ ọmọ Jésè!Àlàáfíà, àlàáfíà fún o,àti àlàáfíà fún àwọn tí ó ràn ó lọ́wọ́,nítorí Ọlọ́run Rẹ̀ yóò ràn ọ́ lọ́wọ́.”Bẹ́ẹ̀ ni Dáfídì sì gbà wọ́n ó sì mú wọn jẹ olórí ẹgbẹ́ ogun.

19 Díẹ̀ nínú àwọn ọkùnrin Mánásè sì yà sí ọ̀dọ̀ Dáfídì nígbà tí ó lọ pẹ̀lú àwọn ará Fílístínì láti bá Ṣọ́ọ̀lù jà. (Òun àti àwọn ọkùnrin Rẹ̀ wọn kò sì ran ará Fílístínì lọ́wọ́ nítorí, lẹ́yìn àjùmọ̀sọ̀rọ̀, àwọn olórí wọn rán wọn jáde, wọ́n sì wí pé Yóò ná wa ní orí wa tí ó bá sì fi sílẹ̀ fún ọ̀gá Rẹ̀ Ṣọ́ọ̀lù).

20 Nígbà tí Dáfídì lọ sí Ṣíkílágì, àwọn wọ̀nyí ni ọkùnrin ti Mánásè ẹnití ó sì yà sọ́dọ̀ Rẹ̀. Ádínà, Jósábádì, Jédíáélì, Míkáẹ́lì, Jósábádì, Élíhù àti Ṣílátì, àwọn olórí ìrẹ́pọ̀ ti ẹgbẹgbẹ̀rún ní Mánásè.

21 Wọ́n sì ran Dáfídì lọwọ lórí ẹgbẹ́ ogun náà, nítorí gbogbo wọn ni akọni ènìyàn àwọn sì tún ni olórí nínú àwọn ọmọogun Rẹ̀.

22 Ọjọ́ dé ọjọ́ ni àwọn ọkùnrin wá láti ran Dáfídì lọ́wọ́, títí tí ó fi ní àwọn ológun ńlá, bí ogun Ọlọ́run,

Àwọn Tókù Darapọ̀ Pẹ̀lú Dáfídì Ní Hébúrónì

23 Àwọn wọ̀nyí sì ni iye ọkùnrin tí ó ti di ìhámọ́ra fún ogun àwọn ẹni tí ó wá sọ́dọ̀ Dáfídì ní Hébúrónì láti yí ìjọba Dáfídì padà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ:

24 Ọkùnrin Júdà, gbé àṣà àti ọ̀kọ̀, ẹgbẹ̀ta lé lọ́gọ́rin (6,080) tí ó ti di ìhámọ́ra fún ogun;

25 Àwọn ọkùnrin Símónì, akọni tó mú fún ogun sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin;

26 Àwọn ọkùnrin Léfì ẹgbàájì ó le ẹgbẹ̀ta (4,600),

27 Pẹ̀lú Jéhóíádà, olórí ìdílé Árónì pẹ̀lú ẹgbẹ̀ẹ́dógún ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ènìyàn (3,700),

28 Àti Sádókì akọni ọ̀dọ́mọkùnrin, pẹ̀lú àwọn (22) méjìlélógún ìjòyè láti ọ̀dọ̀ àwọn ìdílé Rẹ̀;

29 Àwọn arákùnrin Bẹ́ńjámínì ìbátan ọkùnrin Ṣọ́ọ̀lù ẹgbẹ̀ẹ́dógún (3,000), ọ̀pọ̀ nínú àwọn ẹni tí ó si kù ní olóòtọ́ sí ilé Ṣọ́ọ̀lù títí di ìgbà náà;

30 àwọn arákùnrin Éfúráímù, ògbójú akọni, ènìyàn Ọlọ́run ni wọ́n nílé baba wọn ẹgbàwá ó le ẹgbẹ̀rin (20,800)

31 Àwọn ọkùnrin nínú ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè, tí a yàn nípa orúkọ láti wá àti láti yan Dáfídì gẹ́gẹ́ bí ọba-ẹgbàásàn (18,000).

32 Àwọn ọkùnrin Ísákárì, àwọn ẹni tí ó mọ ìgbà yẹn ó sì mọ ohun tí Ísírẹ́lì yóò se ìgbà (200) àwọn ìjòyè, pẹ̀lú gbogbo àwọn ìbátan wọn lábẹ́ òfin wọn.

33 Àwọn ọkùnrin Ṣébúlúnì, àti àwọn jagunjagun tí ó ti nípa ogun múra fún ogun pẹ̀lú orísirísi ohun èlò ìjà, láti ran Dáfídì lọ́wọ́ pẹ̀lú àwọn tí kò fi iyèméjì ṣe ìjólóótọ́ wọn jẹ́ ẹgbàámẹ́dọ́gbọ̀n (50,000);

34 Àwọn ọkùnrin Náfítalì, ẹgbẹ̀rún (1,000) ìjòyè àpapọ̀ pẹ̀lú ẹgbàá méjìdínlógún (36,000) Ọkùnrin tí wọ́n gbé àṣà àti ọ̀kọ̀ wọn.

35 Àwọn ọkùnrin Dánì, tí wọ́n setan fún ogun ẹgbàámẹ́talá (28,600)

36 Àwọn ọkùnrin Áṣérì, àwọn tí ó ti ní ìmọ̀ sójà múra fún ogun ọ̀kẹ́ méje (40,000).

37 Lati ìlà òrùn Jódánì, ọkùnrin Réubénì, Gádì, àti ìdájì ẹ̀yà Mánásè, dìmọ́ra pẹ̀lú gbogbo onírúurú ohun èlò ìjà ọ̀kẹ́ mẹ́fà (120,000).

38 Gbogbo èyí ni àwọn ọkùnrin ológun tí ó fi ara wọn fún ogun láti ṣe iṣẹ fún nínú ẹgbẹ́. Wọ́n wá sí Hébrónì tí ó kún fún ìpinnu láti fi Dáfídì jẹ́ ọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì. Gbogbo àwọn ìyókù lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ́n sì jẹ́ onínú kan láti fi Dáfídì jọba

39 Àwọn ọkùnrin náà lo ọjọ́ mẹ́ta níbẹ̀ pẹ̀lú Dáfídì, wọ́n jẹ, wọ́n sì ń mu, nítorí ìdílé wọn ti pèṣè oúnjẹ fún wọn.

40 Àwọn aládùúgbò láti ọ̀nà jínjìn gẹ́gẹ́ bí Ísákárì, Ṣébúlúnì àti Náfítanì gbé oúnjẹ wá lórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, lórí Ràkunmí, àti lórí ìbáákà àti lórí màlúù, àní oúnjẹ ti ìyẹ̀fun, èṣo àjàrà gbígbẹ, èṣo ọ̀pọ̀tọ́, àkàrà dídùn, ọtí wáìnì, òróró, màlúù àti àgùntàn, nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ayọ̀ wà ní Ísírẹ́lì.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29