1 Kíróníkà 13 BMY

Gbígbé Padà Àpótí Ẹ̀rí

1 Dáfídì sì gbérò pẹ̀lú olúkúlùkù àwọn ìjòyè Rẹ̀, àwọn aláṣẹ ẹgbẹgbẹ̀rún àti àwọn aláṣẹ́ ọgọ́rùn ún

2 Ó sì wí fún gbogbo àwọn ìjọ Ísírẹ́lì pé Tí ó bá dára lójú yín àti tí ó bá ṣe jẹ́ àṣẹ Olúwa Ọlọ́run wa, jẹ́ kí a ránṣẹ́ sí ọ̀nà jínjìn àti gbígbòòrò sí àwọn arákùnrin wa tó kù ní gbogbo àwọn agbègbè ìlú Ísírẹ́lì àti pẹ̀lú àwọn àlùfáà àti àwọn ará Léfì àwọn tí ó wà pẹ̀lú wọn nínú ìlú wọn àti pápá oko tútù, láti wá kó ara wọn jọpọ̀ sọ́dọ̀ wa.

3 Ẹ jẹ́ kí a gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa padà sọ́dọ̀ wa, nítorí wí pé àwa kò ṣe ìwádìí nípa Rẹ̀ ní àsìkò ìjọba Ṣọ́ọ̀lù

4 Gbogbo ìjọ náà sì gbà láti ṣe èyí nítorí ó dàbí wí pé ó tọ lójú gbogbo àwọn ènìyàn.

5 Nígbà náà ni Dáfídì pe gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jọ, láti ọ̀dọ̀ Ṣíhórì ní Éjíbítì lọ sí Lébò ní ọ̀nà à bá wọ Hámátì, láti gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run padà láti Kiriati Jéárímù.

6 Dáfídì àti gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pẹ̀lú Rẹ̀ lọ sí Báláhì ti Júdà (Kiriati-Jéárímù) láti gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run Olúwa tí a fi orúkọ Rẹ̀ pè, tí ó jókòó láàrin kérúbù-gòkè wá.

7 Wọ́n sì gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run láti ilé Ábínádábù lórí kẹ̀kẹ́ túntún, Usà àti Áhíò ń sọ́ ọ.

8 Dáfídì àti gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ni wọ́n ṣe àjọyọ̀ pẹ̀lú gbogbo agbára wọn níwájú Ọlọ́run, pẹ̀lú orin àti pẹ̀lú ohun èlò orin olóhùn gooro, písátérù, tíńbálì, síńbálì àti ìpè.

9 Nígbà tí wọ́n dé sí ilẹ̀ pakà ti Kídónì, Úsà na ọwọ́ Rẹ̀ síta láti di àpótì ẹ̀rí Olúwa mú, nítorí màlúù kọ̀ṣẹ̀.

10 Ìbínú Olúwa, sì ru sí Úsà, ó sì lùú bolẹ̀ nítorí o ti fi ọwọ́ Rẹ̀ lórí Àpótí ẹ̀rí. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì kú síbẹ̀ níwájú Ọlọ́run.

11 Nígbà náà Dáfídì sì bínú nítorí ìbínú Olúwa ké jáde lórí Úsá, àti títí di òní, wọ́n sì ń pe ibẹ̀ ní péresì-Ùsà.

12 Dáfídì sì bẹ̀rù Ọlọ́run ní ọjọ́ náà, ó sì bèèrè pé, Báwo ni èmi náà ó ṣe gbé àpótí ẹ̀rí Olórun sí ọ̀dọ̀ mi?

13 Kò gbé àpótí ẹ̀rí náà wá sí ọ̀dọ̀ ará Rẹ̀ ní ìlú ti Dáfídì dípò èyí, ó sì gbé e sí ẹ̀gbé, sí ilé Obedi-Édómù ará Gítì.

14 Àpótí ẹ̀rí Olúwa sì wà lọ́dọ̀ àwon ará ilé Obedi-Édómù ní ilé Rẹ̀ fún oṣù mẹ́ta, Olúwa sì bùkún agbo ilé àti gbogbo ohun tí ó ní.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29