1 Kíróníkà 29 BMY

Ẹ̀bùn Fún Kíkọ́ Ilé Olúwa.

1 Nígbà náà, ọba Dáfídì sọ fún gbogbo àpéjọ pé: “Ọmọ mi Sólomónì, èyí tí Ọlọ́run ti yàn, ṣì kéré ó sì jẹ́ aláìmòye. Iṣẹ́ náà tóbi, nítorí ìkọ́lé bí ti ààfin kì í ṣe fún ènìyàn ṣùgbọ́n fún Olúwa Ọlọ́run.

2 Pẹ̀lu gbogbo ìrànlọ́wọ́ mi èmi ti pèsè fún ilé Ọlọ́run mi wúrà fún iṣẹ́ wúrà, fàdákà fún ti fàdákà, òjíá fún ti òjíá, irin fún ti irin àti igi fún ti igi àti òkúta oníyebíye fún títọ́ Rẹ̀, (túríkúóṣè) òkúta lóríṣíríṣí, àmọ̀ àti oríṣìíríṣìí ẹ̀yà òkúta àti òkuta dáradára kan gbogbo wọ̀nyí ní iye púpọ̀.

3 Yàtọ̀ fún èyí, nínú ìfọkànsìn mi sí ilé Ọlọ́run mi, èmí fi ìṣúra mi tìkalára mí ti wúrà àti fàdákà fún ilé Ọlọ́run mi, jù gbogbo Rẹ̀ lọ, èmi ti pèṣè fún ilé mímọ́ ti Olúwa yìí:

4 Ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) talẹ́ntì wúrà (wúrà ti ofírì) àti ẹgbẹ̀rin méje tálẹ́ntì fàdákà tí a yọ̀rọ̀ kúrò, fún bíbo àwọn ògiri ilé náà.

5 Fún iṣẹ́ wúrà àti fàdákà náà, àti fún orísìí iṣẹ́ ti ó yẹ ní ṣíṣe nípaṣẹ̀ àwọn tí ó ní òye oríṣíiríṣí iṣẹ́. Níṣinṣìn yìí, ta ni ó ní ìfẹ́ sí yíya ará Rẹ̀ sọ́tọ̀ lónìí sí Olúwa?”

6 Nígbà náà àwọn aṣájú àwọn ìdílé, àwọn ìjòyè àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì, àwọn alákòóṣo ẹgbẹgbẹ̀wá àti alákòóṣo ọrọrún àti àwọn oníṣẹ́ tí ó wà ní ìdí iṣẹ́ ọba ní ìfẹ́ sí i.

7 Wọ́n fi sílẹ̀ fún iṣẹ́ lórí ilé Ọlọ́run, ẹgbẹ̀rún márùn-ún talẹ́ntì àti ẹgbẹ̀rin mẹ́wàá (Dáríkì) wúrà, ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá talẹ́ntì fàdákà, ẹgbẹ̀rin méjìdínlógún talẹ́ntì òjíá àti ọgọ́rin ẹgbẹ̀rin talẹ́ntì irin.

8 Ẹnikẹ́ni tí ó ní òkúta iyebíye fi wọn sí ilé ìṣúra ilé Ọlọ́run ní ìhámọ́ Jéhíélì ará Géríṣónì.

9 Àwọn ènìyàn láyọ̀ nínú ìṣesí àtọkànwá fi sílẹ̀ àwọn olórí wọn, nítorí tí wọ́n ti fi sílẹ̀ ní ọ̀fẹ́ pẹ̀lú gbogbo ọkàn sí Olúwa. Dáfídì ọba pẹ̀lú yọ̀ gidigidi.

Àdúrà Dáfídì.

10 Dáfídì yin Olúwa níwájú gbogbo àwọn tí ó péjọ, wí pé,“Ìyìn ni fún Ọ, Olúwa,Ọlọ́run baba a wa Ísírẹ́lì,láé àti láéláé.

11 Tìrẹ Olúwa ni títóbi àti agbára pẹ̀lú ìyìnàti ọlá ńlá àti dídán,nítorí tí gbogbo nǹkan ní ọ̀run àti ayé jẹ́ tìrẹ.Tìrẹ Olúwa ni ìjọba;a gbé ọ ga gẹ́gẹ́ bí orí lórí ohun gbogbo.

12 Ọlá àti ọ̀wọ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Rẹ;ìwọ ni alákòóso gbogbo nǹkan.Ní ọwọ́ rẹ ni ipá àti agbára wà láti gbéga àtiláti fi agbára fún ohun gbogbo.

13 Nísinsìn yìí, Ọlọ́run wa, àwa fi ọpẹ́ fún Ọ,a sì fi ìyìn fún orúkọ Rẹ̀ tí ó lógo.

14 “Ṣùgbọ́n Ta ni èmi, àti ta ni àwọn ènìyàn mi, tí a fi lè fi sílẹ̀ tinútínú bí irú èyí? Gbogbo nǹkan wá láti ọ̀dọ̀ rẹ, àwa sì ti fífún ọ láti ara ohun tí ó wá láti ọwọ́ rẹ.

15 Àwa jẹ́ àjèjì àti àlejò ní ojú rẹ gẹ́gẹ́ bí baba ńlá a wa, àwọn ọjọ́ wa lórí ilẹ̀ ayé rí bí òjìji láìsí ìrètí.

16 Olúwa Ọlọ́run wa tí fi gbogbo pípọ̀ yìí tí àwa ti pèṣè fún kíkọ́ ilé Olúwa fun orúkọ, mímọ́ Rẹ̀, ó wá láti ọwọ́ ọ̀ rẹ, gbogbo Rẹ̀ sì jẹ́ tirẹ̀.

17 Èmi mọ̀ Ọlọ́run mi, wí pé ìwọ̀ dán ọkàn wò, ó sì tẹ́ ọ lọ́rùn pẹ̀lú òtítọ́ inú. Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni èmi ti fi sílẹ̀ pẹ̀lú tìfẹ́tìfẹ́ pẹ̀lú òtítọ́. Nísinsìn yìí èmi ti ríi pẹ̀lú ayọ̀ bí àwọn ènìyàn yìí tí ó wà níbí ti fi fún ọ pẹ̀lú tìfẹ́tìfẹ́.

18 Olúwa Ọlọ́run àwọn baba a wa Ábúráhámù, Ísákì àti Ísírẹ́lì pa ìfẹ́ yìí mọ́ ninú ọkàn àwọn ènìyàn rẹ títí láé pẹ̀lú pípa ọkàn mọ́ lóòtọ́ sí ọ.

19 Àti fún ọmọ mi Sólómónì ní ìfọkànsìn tòótọ́ láti pa àṣẹ rẹ mọ́ àwọn ohun tí ó nílò àti òfin àti láti ṣe ohun gbogbo láti kọ́ ààfin bí ti ọba fún èyí tí mo ti pèsè.”

20 Dáfídì sì sọ fún gbogbo ìjọ ènìyàn pé, Nísinsìn yìí, ẹ fi ìyìn fún Olúwa Ọlọ́run yín. Gbogbo ènìyàn sì fi ìyìn fún Olúwa Ọlọ́run àwọn baba wọn, wọ́n sì tẹ orí wọn ba, wọ́n wólẹ̀ fún Olúwa àti ọba.

A yan Sólómónì Gẹ́gẹ́ bí Ọba.

21 Ni ọjọ́ kejì, wọ́n rú ẹbọ sí Olúwa, wọ́n sì rú ẹbọ ọrẹ ṣíṣun sí i: ẹgbẹ̀rún kan akọ màlúù, ẹgbẹ̀rin kan àgbò, àti ẹgbẹ̀rin kan akọ ọ̀dọ́ àgùntàn. Lápapọ̀ pẹ̀lú ọrẹ mímu àti àwọn ẹbọ mìíràn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ fún gbogbo Ísírẹ́lì.

22 Wọ́n jẹ wọ́n sì mu pẹ̀lú ayọ̀ kíkún ní iwájú Olúwa ní ọjọ́ náà.Nígbà náà wọ́n yan Sólómonì ọmọ Dáfídì gẹ́gẹ́ bí ọba lẹ́ẹ̀kejì wọ́n fi àmì òróró yàn án níwájú Olúwa láti ṣe olórí àti Ṣádókù láti ṣe àlùfáà.

23 Bẹ́ẹ̀ ni Sólómónì jókòó lórí ìtẹ́ Olúwa gẹ́gẹ́ bí ọba ní ipò bàbá a Rẹ̀ Dáfídì. O ṣe àṣeyọrí, gbogbo Ísírẹ́lì sì gbọ́ràn sí i lẹ́nu.

24 Gbogbo àwọn ìjòyè àti àwọn ọkùnrin alágbára, pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ ọba Dáfídì tẹrí ara wọn ba fún ọba Sólómónì.

25 Olúwa gbé Solómónì ga púpọ̀ ní ojú gbogbo Ísírẹ́lì, ó sì kẹ́ ẹ ní ìkẹ́ ọlá ńlá, ní irú èyí tí a kò kẹ́ ọba kankan ṣáájú Rẹ̀ tí ó jẹ lórí Ísírẹ́lì.

Ikú Dáfídì.

26 Dáfídì ọmọ Jéṣè jẹ́ ọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì.

27 Ó jọba lórí Ísírẹ́lì fún ogójì ọdún; ọdún méje ni ó jọba ní Hẹ́súrónì, ó sì jọba ní ọdún mẹ́talélọ́gbọ̀n (33) ní Jérúsálẹ́mù.

28 Òun sì darúgbó, ó sì kú ikú rere, ó gbádùn ẹ̀mí gígùn, ọlá àti ọrọ̀. Sólómónì ọmọ Rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò Rẹ̀

29 Ní ti ohun tí ó ṣẹlẹ̀ nígbà ìjọba ọba Dáfídì, láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin, a kọ wọ́n sínú ìwe ìrántí ti Sámúẹ́lì aríran, ìwé ìrántí ti Nátanì wòlíì àti ìwé ìrántí ti Gádì aríran,

30 lápapọ̀, pẹ̀lú gbogbo ìjọba àti agbára Rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìgbà tí ó kọjá lórí Rẹ̀, àti lórí Ísírẹ́lì, àti lórí gbogbo àwọn ìjọba gbogbo ilẹ̀ náà.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29