1 Gbogbo àwọn Ísírẹ́lì kó ara wọn jọ pọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ Dáfídì ní Hébúrónì wọ́n sì wí pé, “Àwa ni ẹran ara rẹ àti ẹ̀jẹ̀ rẹ.
2 Ní àtijọ́, kódà nígbà tí Ṣọ́ọ̀lù jẹ ọba, ìwọ ni ẹni tí ó darí Ísírẹ́lì ní ojú ogun wọn. Olúwa Ọlọ́run rẹ sì wí fún ọ pé, ‘Ìwọ yóò sì jẹ́ olùsọ́ àgùntàn fún àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì, ìwọ yóò sì jẹ́ olórí fún wọn.’ ”
3 Nígbà tí gbogbo àwọn ìjòyè Ísírẹ́lì tí wọ́n ti wá sọ́dọ̀ ọba Dáfídì ni Hébúrónì. Ó sì ṣe májẹ̀mú pẹ̀lú wọn ní Hébúrónì níwájú Olúwa, wọ́n sì fi àmìn òróró yan Dáfídì ọba lórí Ísírẹ́lì, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti ṣèlérí láti ọ̀dọ̀ Ṣámúẹ́lì.
4 Dáfídì àti gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde lọ sí Jérúsálẹ́mù (tí se Jébúsì) Àwọn ara Jébúsì ẹni tí ń gbé níbẹ̀.