9 Ọgọ́rin nínú àwọn ọmọ Hébírónì;Élíélì olórí àti àwọn ẹbí Rẹ̀.
10 Méjìléláàdọ́fà nínú àwọn ọmọ Húsíélì;Ámínádábù olórí àti àwọn ẹbí Rẹ̀.
11 Dáfídì sì ránṣẹ́ pe Ṣádókù, Ábíátarì tí wọ́n jẹ́ àlùfáà, àti Úríélì, Ásáíà. Jóẹ́lì, Ṣémáíà, Élíélì àti Ámínádábù tí wọ́n jẹ́ Léfì.
12 Ó sì fí fún wọn pé, Ẹ̀yin ni olórí àwọn ìdílé Léfì; ẹ̀yin àti àwọn Léfì ènìyàn yín, ẹ ya ara yín sí mímọ́ kí ẹ lè gbé àpótí-ẹ̀rí Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, lọ sí ibi tí mó ti pèsè sílẹ̀ fún un.
13 Nítorí tí ẹ̀yin ọmọ Léfì kò gbe gòkè wá ní ìgbà àkọ́kọ́ ti Olúwa Ọlọ́run wa ya ìbínú Rẹ̀ lù wá. Àwa kò sì ṣe ìwádìí lọ́wọ́ Rẹ̀ nípa bí a ti ń ṣe é gẹ́gẹ́ bí ọ́nà tí a là sílẹ̀.
14 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn àlùfáà àti àwọn Léfì ya ara wọn sí mímọ́ láti gbé àpótí-ẹ̀rí Olúwa gòkè wá, Ọlọ́run Ísírélì.
15 Nígbà náà ni àwọn Léfì gbé àpótí-ẹ̀rí Ọlọ́run pẹ̀lú ọ̀pá ní èjìká wọn. Gẹ́gẹ́ bí Mósè ti paá láṣẹ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa.