19 Nígbà tí wọn kéré ní iye,wọ́n kéré gidigidi, wọ́n sì jẹ́ àlejò níbẹ̀,
20 wọ́n rìn kiri láti orílẹ̀ èdè sí orílẹ̀-èdèláti ìjọba kan sí èkejì.
21 Kò gba ọkùnrin kankan láyè láti pọ́n wọn lójú;nítorí ti wọn, ó bá àwọn ọba wí.
22 “Má ṣe fọwọ́ kan àwọn ẹni àmì òróró mi;Má ṣe pa àwọn wòlíì mi lára.”
23 Kọrin sí Olúwa gbogbo ayé;ẹ máa fi ìgbàlà Rẹ̀ hàn láti ọjọ́ dé ọjọ́.
24 Kéde ìgbàlà à Rẹ̀ láàárin àwọn orílẹ̀-èdè,ohun ìyàlẹ́nu tí ó se láàrin gbogbo ènìyàn.
25 Nítorí títóbi ni Olúwa òun sì ni ìyìn yẹ Jùlọ;òun ni kí a bẹ̀rù ju gbogbo àwon Ọlọ́run lọ.