23 Kọrin sí Olúwa gbogbo ayé;ẹ máa fi ìgbàlà Rẹ̀ hàn láti ọjọ́ dé ọjọ́.
24 Kéde ìgbàlà à Rẹ̀ láàárin àwọn orílẹ̀-èdè,ohun ìyàlẹ́nu tí ó se láàrin gbogbo ènìyàn.
25 Nítorí títóbi ni Olúwa òun sì ni ìyìn yẹ Jùlọ;òun ni kí a bẹ̀rù ju gbogbo àwon Ọlọ́run lọ.
26 Nítorí gbogbo àwọn Ọlọ́run orílẹ̀ èdè jẹ́ àwọn òrìsà,ṣùgbọ́n Olúwa dá àwọn ọ̀run.
27 Dídán àti ọlá-ńlá ni ó wà ní wájú Rẹ̀;agbára àti ayọ̀ ni ó wà ní ibi ibùgbé Rẹ̀.
28 Fifún Olúwa, ẹ̀yin ìdílé àwọn orílẹ̀-èdè,ẹ fi ògo àti ipá fún Olúwa,
29 fún Olúwa ní ìyìn nítorí orúkọ Rẹ̀.Gbé ọrẹ kí ẹ sì wá ṣíwájú Rẹ̀;Sìn Olúwa nínú inú dídùn ìwà mímọ́ Rẹ̀.