26 Nítorí gbogbo àwọn Ọlọ́run orílẹ̀ èdè jẹ́ àwọn òrìsà,ṣùgbọ́n Olúwa dá àwọn ọ̀run.
27 Dídán àti ọlá-ńlá ni ó wà ní wájú Rẹ̀;agbára àti ayọ̀ ni ó wà ní ibi ibùgbé Rẹ̀.
28 Fifún Olúwa, ẹ̀yin ìdílé àwọn orílẹ̀-èdè,ẹ fi ògo àti ipá fún Olúwa,
29 fún Olúwa ní ìyìn nítorí orúkọ Rẹ̀.Gbé ọrẹ kí ẹ sì wá ṣíwájú Rẹ̀;Sìn Olúwa nínú inú dídùn ìwà mímọ́ Rẹ̀.
30 Wárìrì níwájú Rẹ̀, gbogbo ayé!Ayé sì fi ìdímúlẹ̀; a kò sì le è síi.
31 Jẹ́ kí àwọn ọ̀run kí ó yọ̀ Jẹ́ kí ayé kí ó ṣe inú dídùn;Jẹ́ kí wọn kí ó sọ láàárin àwọn orílẹ̀ èdè, pé “Olúwa jọba!”
32 Jẹ́ kí ọ̀run kí ó tún dún padà, ati gbogbo ohun tí ó wà nínú Rẹ̀;Jẹ́ kí àwọn pápá kí ó hó fún ayọ̀, àti gbogbo ohun tí ó wà nínú Rẹ̀!