29 fún Olúwa ní ìyìn nítorí orúkọ Rẹ̀.Gbé ọrẹ kí ẹ sì wá ṣíwájú Rẹ̀;Sìn Olúwa nínú inú dídùn ìwà mímọ́ Rẹ̀.
30 Wárìrì níwájú Rẹ̀, gbogbo ayé!Ayé sì fi ìdímúlẹ̀; a kò sì le è síi.
31 Jẹ́ kí àwọn ọ̀run kí ó yọ̀ Jẹ́ kí ayé kí ó ṣe inú dídùn;Jẹ́ kí wọn kí ó sọ láàárin àwọn orílẹ̀ èdè, pé “Olúwa jọba!”
32 Jẹ́ kí ọ̀run kí ó tún dún padà, ati gbogbo ohun tí ó wà nínú Rẹ̀;Jẹ́ kí àwọn pápá kí ó hó fún ayọ̀, àti gbogbo ohun tí ó wà nínú Rẹ̀!
33 Nígbà náà ni igi ti ọ̀dàn yóò kọrin,Wọn yóò kọrin fún ayọ̀ níwájú Olúwa, Nítorí tí ó wá láti sèdájọ́ ayé.
34 Fi ọpẹ fún Olúwa, nítórí tí ó dára;ìfẹ́ ẹ Rẹ̀ dúró títí láé.
35 Sunkún jáde, “Gbà wá, Ọlọ́run Olùgbàlà a wa;kówajọ kí o sì gbà wá kúrò lọ́wọ́ àwọn orílẹ̀ èdè,kí àwa kí ó lè fí ọpẹ́ fún orúkọ mímọ́ rẹ,kí àwa kí ó lè yọ̀ nínú ìyìn Rẹ̀.”