1 Kíróníkà 19:2-8 BMY

2 Dáfídì rò wí pé Èmi yóò fi inú rere hàn sí Hánúnì ọmọ Náháṣì, nítorí baba a Rẹ̀ fi inú-rere hàn sí mi. Bẹ́ẹ̀ ni, Dáfídì rán àwọn aṣojú lọ láti lọ fi ìbákẹ́dùn Rẹ̀ hàn sí Hánúnì níti baba a Rẹ̀.Nígbà tí àwọn ọkùnrin Dáfídì wá sí ọ̀dọ̀ Hánúnì ní ilẹ̀ Àwọn ará Ámónì láti fi ìbákẹ́dùn Rẹ̀ hàn sí i,

3 Àwọn ọkùnrin ọlọ́lá ti Ámónì sọ fún Hánúnì pé, Ṣé ìwọ rò pé Dáfídì ń bu ọlá fún Baba rẹ nípa rírán àwọn ọkùnrin sí ọ láti fi ìbákẹ́dùn Rẹ̀ hàn.? Ṣé àwọn ọkùnrin Rẹ̀ kò wá sí ọ̀dọ̀ rẹ láti wá kiri àti samí sita orílẹ̀ èdè àti láti bì í ṣubú.

4 Bẹ́ẹ̀ ni Hanúnì fi ipá mú àwọn ọkùnrin Dáfídì, fá irun wọn, wọ́n gé ẹ̀wù wọn kúrò ní àárin ìdí Rẹ̀, ó sì rán wọn lọ.

5 Nígbà tí ẹnìkan wá, tí ó sì sọ fún Dáfídì nípa àwọn ọkùnrin Rẹ̀, ó rán àwọn ìránṣẹ́ láti lọ bá wọn, nítorí wọ́n ti di rírẹ̀ sílẹ̀ gidigidi. Ọba wí pe, Dúró ní Jeríkò títí tí irungbọ̀n yín yóò fi hù, Nígbà náà ẹ padà wá.

6 Nígbà tí àwọn ará Ámónì rí i wí pé wọ́n ti di ẹ̀ṣẹ̀ ní ihò imú Dáfídì, Hánúnì àti àwọn ará Ámónì rán ẹgbẹ̀rún talẹ́ntì fàdákà láti gba iṣẹ́ àwọn kẹ̀kẹ́ àti àwọn agun-kẹ̀kẹ́ láti síríà Náháráímù, Ṣíríà Mákà àti Ṣóbà.

7 Wọ́n gba iṣẹ́ ẹgbẹ̀rin méjìlélọ́gbọ̀n kẹ̀kẹ́ àti agun-kẹ̀kẹ́ àti ọba Mákà pẹ̀lú àwọn ọ̀wọ́-ọmọ ogun Rẹ̀ tí ó wá pàgọ́ ní ẹ̀bá Médébà, nígbà tí àwọn ará Ámónì kó jọ pọ̀ láti ìlú wọn, tí wọ́n sì jáde lọ fún ogun.

8 Ní gbígbọ́ eléyìí, Dáfídì rán Jóábù jáde pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ ogun ọkùnrin tí ó le jà.