1 Kíróníkà 19:4-10 BMY

4 Bẹ́ẹ̀ ni Hanúnì fi ipá mú àwọn ọkùnrin Dáfídì, fá irun wọn, wọ́n gé ẹ̀wù wọn kúrò ní àárin ìdí Rẹ̀, ó sì rán wọn lọ.

5 Nígbà tí ẹnìkan wá, tí ó sì sọ fún Dáfídì nípa àwọn ọkùnrin Rẹ̀, ó rán àwọn ìránṣẹ́ láti lọ bá wọn, nítorí wọ́n ti di rírẹ̀ sílẹ̀ gidigidi. Ọba wí pe, Dúró ní Jeríkò títí tí irungbọ̀n yín yóò fi hù, Nígbà náà ẹ padà wá.

6 Nígbà tí àwọn ará Ámónì rí i wí pé wọ́n ti di ẹ̀ṣẹ̀ ní ihò imú Dáfídì, Hánúnì àti àwọn ará Ámónì rán ẹgbẹ̀rún talẹ́ntì fàdákà láti gba iṣẹ́ àwọn kẹ̀kẹ́ àti àwọn agun-kẹ̀kẹ́ láti síríà Náháráímù, Ṣíríà Mákà àti Ṣóbà.

7 Wọ́n gba iṣẹ́ ẹgbẹ̀rin méjìlélọ́gbọ̀n kẹ̀kẹ́ àti agun-kẹ̀kẹ́ àti ọba Mákà pẹ̀lú àwọn ọ̀wọ́-ọmọ ogun Rẹ̀ tí ó wá pàgọ́ ní ẹ̀bá Médébà, nígbà tí àwọn ará Ámónì kó jọ pọ̀ láti ìlú wọn, tí wọ́n sì jáde lọ fún ogun.

8 Ní gbígbọ́ eléyìí, Dáfídì rán Jóábù jáde pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ ogun ọkùnrin tí ó le jà.

9 Àwọn ará Ámónì jáde wá, wọ́n sì dá isẹ́ ogun ní àbáwọlé sí ìlú ńlá wọn, nígbà tí àwọn ọba tí ó wá, fún rara wọn wà ni orílẹ̀ èdè tí ó sí sílẹ̀.

10 Jóábù ri wí pé àwọn ìlà ogun wà níwájú àti ẹ̀yìn òun; Bẹ́ẹ̀ ni ọmọ ogun tí ó dára ní Ísírẹ́lì, o sì tẹ́ ogun wọn sí àwọn ará Ṣíríà.