50 Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Kélẹ́bù.Àwọn ọmọ Húrì, àkọ́bí Éfúrátà:Ṣóbálì baba Kiriati-Jéárímù.
51 Ṣálímà baba Bétíléhẹ́mù àti Háréfù baba Bẹti-Gádérì.
52 Àwọn ọmọ Ṣóbálì baba Kíríátì-Jéárímù ni:Háróè, ìdajì àwọn ará Mánáhítì.
53 Àti ìdílé Kíríátì-Jéárímù: àti àwọn ara Ítírì, àti àwọn ará Pútì, àti àwọn ará Ṣúmátì àti àwọn ará Mísíhí-ráì: láti ọ̀dọ̀ wọn ni àwọn ọmọ ará Sórátì àti àwọn ará Ésítaólì ti wá.
54 Àwọn ọmọ Ṣálímà:Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, àti àwọn ará Nétófátì, Atírótì Bẹti-Jóábù, ìdajì àwọn ará Mánátì, àti Ṣórì,
55 Àti àwọn ìdílé àwọn akọ̀wé, ẹni tí ń gbé ní Jábésì: àti àwọn ọmọ Tírátì àti àwọn ará Ṣíméátì àti àwọn ará Ṣúkátì. Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ará Kénì, ẹni tí ó wá láti ọ̀dọ̀ Hámátì, baba ilé Kélẹ́bù.