1 Sátanì sì ru ọkàn Dáfídì sókè láti ka iye Ísírẹ́lì.
2 Bẹ́ẹ̀ ni Dáfídì sì wí fún Jóábù àti àwọn olórí ti àwọn ọ̀wọ́ ọmọ ogun, Lọ kí o lọ ka iye àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti Béríṣébà títí dé Dánì. Kí o sì padà wá sọ fún mi kí èmi kí ó le mọ iye tí wọ́n jẹ́.
3 Ṣùgbọ́n Jóábù dá a lóhùn pé Kí Olúwa pọ̀ sí ní ìgbà ọgọ́rùn ún ju ti tẹ́lẹ̀ lọ Olúwa ọba mi, sé gbogbo wọn kì í ṣe ìránṣẹ́ Olúwa ni? Kí ni ó dé tí Olúwa mi ṣe fẹ́ ṣèyí? Kí ni ó de tí yóò fi mú Ísírẹ́lì jẹ̀bi?
4 Ọ̀rọ̀ ọba, bí ó ti wù kí ó rí, borí tí Jóábù. Bẹ́ẹ̀ ni Jóábù kúrò ó sì jáde lọ sí Jérúsálẹ́mù.