10 “Lọ kí o lọ sọ fún Dáfídì pé, ‘Èyí ní ohun tí Olúwa sọ: Èmi sì fún ọ ní àwọn àṣàyàn mẹ́ta. Yan ọ̀kan ninú wọn fún mi láti gbé jáde nípa rẹ.’ ”
11 Bẹ́ẹ̀ ni Gádì lọ sí ọ̀dọ̀ Dáfídì ó sì wí fún pé, “Nǹkan yí ni ohun tí Olúwa sọ: ‘Yan aṣàyàn tìrẹ:
12 Ọdún mẹ́ta ìyàn, oṣù mẹ́ta gbígbá lọ niwájú àwọn ọ̀tá rẹ, pẹ̀lú idà wọn láti lé ọ bá, tàbí ọjọ́ mẹ́fà idà Olúwa ọjọ́ àjàkálẹ̀-àrùn ní ilẹ̀ náà, pẹ̀lú àwọn ángẹ́lì Olúwa láti pa gbogbo agbègbè Ísírẹ́lì run.’ Nísinsi yìí ǹjẹ́, ronú bí èmi yóò ti ṣe dá ẹni tí ó rán mi lóhùn.”
13 Dáfídì sì wí fún Gádì pé èmi wà nínú ìyọnu ńlá. Jẹ́ kí èmi kí ó ṣubú sí ọwọ́ Olúwa, nítorí tí àánú Rẹ̀ pọ̀ gidigidi; Ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí èmi kí o ṣubú sí ọwọ́ àwọn ènìyàn.
14 Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa rán àjàkálẹ̀-àrùn lórí Ísírẹ́lì, ẹgbàá márùndínlógójì (70,000) ènìyàn Ísírẹ́lì sì kú.
15 Ọlọ́run sì rán ańgẹ́lì láti pa Jérúsálẹ́mù run. Ṣùgbọ́n bí áńgẹ́lì ti ń ṣe èyí, Olúwa sì ríi. Ó sì káàánú nítorí ibi báà, ó sì wí fún áńgẹ́lì tí ó pa àwọn ènìyàn náà run pé, “Ó ti tó! Dá ọwọ́ rẹ dúró.” Ańgẹ́lì Olúwa náà sì dúró níbi ilẹ̀ ìpakà Áráúnà ará Jébúsì.
16 Dáfídì sì wòkè ó sì rí áńgẹ́lì Olúwa dúró láàrin ọ̀run àti ayé pẹ̀lú idà fífàyọ ní ọwọ́ Rẹ̀ tí ó sì nàá sórí Jérúsálẹ́mù. Nígbà náà Dáfídì àti àwọn àgbààgbà, sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀, wọ́n sì da ojú wọn bolẹ̀.