6 Ṣùgbọ́n Jóábù kó àwọn Léfì àti Bẹ́ńjámínì mọ́ iye wọn, nítorí àsẹ ọba jẹ́ ìríra fún un.
7 Àṣẹ yìí pẹ̀lú sì jẹ́ búburú lójú Olúwa, bẹ́ẹ̀ ni ó sì díyàjẹ Ísírẹ́lì.
8 Nígbà náà Dáfídì sọ fún Ọlọ́run pé, Èmi ti dẹ́ṣẹ̀ gidìgidì nípa ṣíṣe èyí. Nísinsin yìí, èmi bẹ̀ ọ́, mú ìjẹ̀bi àwọn ìránṣẹ́ rẹ kúrò. Èmi ti hùwà òmùgọ̀ gidigidi.
9 Olúwa sì fi fún Gádì, aríran Dáfídì pé.
10 “Lọ kí o lọ sọ fún Dáfídì pé, ‘Èyí ní ohun tí Olúwa sọ: Èmi sì fún ọ ní àwọn àṣàyàn mẹ́ta. Yan ọ̀kan ninú wọn fún mi láti gbé jáde nípa rẹ.’ ”
11 Bẹ́ẹ̀ ni Gádì lọ sí ọ̀dọ̀ Dáfídì ó sì wí fún pé, “Nǹkan yí ni ohun tí Olúwa sọ: ‘Yan aṣàyàn tìrẹ:
12 Ọdún mẹ́ta ìyàn, oṣù mẹ́ta gbígbá lọ niwájú àwọn ọ̀tá rẹ, pẹ̀lú idà wọn láti lé ọ bá, tàbí ọjọ́ mẹ́fà idà Olúwa ọjọ́ àjàkálẹ̀-àrùn ní ilẹ̀ náà, pẹ̀lú àwọn ángẹ́lì Olúwa láti pa gbogbo agbègbè Ísírẹ́lì run.’ Nísinsi yìí ǹjẹ́, ronú bí èmi yóò ti ṣe dá ẹni tí ó rán mi lóhùn.”