15 Ìwọ sì ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn oníṣẹ́ ènìyàn: àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà, àti àwọn oníṣọ̀nà òkúta àti àwọn agbẹ́-òkúta, àti gẹ́gẹ́ bí onírúurú ọlọ́gbọ́n ènìyàn ní gbogbo onírúurú iṣẹ́.
16 Nínú wúrà, fàdákà àti idẹ àti irin onísọ̀nà tí kò ní ìwọ̀n. Nísinsin yìí bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́, kí Olúwa wà pẹ̀lú rẹ.”
17 Nígbà náà Dáfídì pa á láṣẹ fún gbogbo àwọn àgbààgbà ní Ísírẹ́lì láti ran Sólónmónì ọmọ Rẹ̀ lọ́wọ́.
18 Ó sì wí pé, “Ṣé kò sí Olúwa Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú rẹ? Òun kò ha ti fi ìsinmi fún ọ lórí gbogbo ilẹ̀? Nítorí ó sì ti fi àwọn tí ń gbé ní ilẹ̀ náà lé mi lọ́wọ́ ó sì ti fi ìsẹ́gun fún ilẹ̀ náà níwájú Olúwa àti níwájú àwọn ènìyàn.
19 Nísinsìn yìí ẹ sí ọkàn yin payá àti àyà yín sí àti wá Olúwa Ọlọ́run yín. Bẹ́ẹ̀ sì ni kọ́ ibi mímọ́ fún Olúwa Ọlọ́run. Bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ kí ó le gbé àpótí ẹ̀rí ti májẹ̀mú Olúwa àti ohun èlò mímọ́ tí ó jẹ́ ti Ọlọ́run, sínú ilé Olúwa tí a o kọ́ fún orúkọ Olúwa.”