3 Ó sì pèsè ọ̀pọ̀lọpọ̀ iye irin láti fi ṣe ìṣọ́ fún àwọn ìlẹ̀kùn ẹnu ọ̀nà àti fún idẹ; àti fún òpó idẹ ni àìní ìwọ̀n.
4 Ó sì tún pèsè ọ̀pọ̀lọpọ̀ igi Kédárì tí ó jẹ́ àìníye, nítorí pé àwọn ará Ṣídónì àti àwọn ará Tírè mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ igi kédárì wá fún Dáfídì.
5 Dáfídì wí pé, Ọmọ mi Sólómónì ọ̀dọ́mọdé ni ó sì jẹ́ aláìní ìríri, ilé tí a ó kọ́ fún Olúwa gbọdọ̀ jẹ́ títóbi jọjọ, kí ó sì ní òkìkí àti ògo jákèjádò gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè. Nítorí náà ni èmi yóò ṣe pèsè sílẹ̀ fún un. Bẹ́ẹ̀ ni Dáfídì sì ṣe ìpèsè sílẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ kí ó tó di wí pé ó kú.
6 Nígbà náà ó pe Sólómónì ọmọ Rẹ̀ ó sì sọ fun pé kí ó kọ́ ilé fún-un Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì.
7 Dáfídì sì wí fún Sólómónì pé, “Ọmọ mi, mo sì ní-in ní ọkàn mi láti kọ́ ilé fún orúkọ Olúwa Ọlọ́run mi.
8 Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé: ‘Ìwọ ti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀, o sì ti ja ọ̀pọ̀ ogun ńlá ńlá, kì í ṣe ìwọ ni yóò kọ́ ilé fún orúkọ mi, nítorí Ìwọ ti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ púpọ̀ lórí ilẹ̀ ní ojú mi.
9 Ṣùgbọ́n ìwọ yóò ní ọmọ tí yóò sì jẹ́ ọkùnrin onírẹ̀lẹ̀ àti onísinmi, Èmi yóò sì fún-un ní ìsinmi láti ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn ọ̀ta Rẹ̀ lórí gbogbo ilẹ̀ yíká. Orúkọ Rẹ̀ yóò sì máa jẹ́ Sólómónì, Èmi yóò sì fi àlàáfíà àti ìdákẹ́jẹ́ fún Ísírẹ́lì lásìkò ìjọba Rẹ̀.