1 Nígbà tí Dáfídì sì dàgbà tí ó sì kún fún ọjọ́, ó sì fi Sólómónì ọmọ Rẹ̀ jẹ ọba lórí Ísírẹ́lì.
2 Ó sì kó gbogbo àgbààgbà Ísírẹ́lì jọ, àti gẹ́gẹ́ bí àwọn àlùfáà àti àwọn ará Léfì.
3 Àwọn ọmọ Lefì lati ọgbọ̀n ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ni wọ́n kà àpapọ̀ iye àwọn ọkùnrin wọn sì jẹ́ ẹgbàá mọ́kàndínlógún (38,000)
4 Dáfídì sì wí pe, Níti èyí, ẹgbàáméjìlá (24,000) ni kí wọn jẹ́ alábojútó iṣẹ́ ilé fún Olúwa àti ẹgbàáta (6,000) ni kí ó ṣe olórí àti onídàájọ́.