2 Ó sì kó gbogbo àgbààgbà Ísírẹ́lì jọ, àti gẹ́gẹ́ bí àwọn àlùfáà àti àwọn ará Léfì.
3 Àwọn ọmọ Lefì lati ọgbọ̀n ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ni wọ́n kà àpapọ̀ iye àwọn ọkùnrin wọn sì jẹ́ ẹgbàá mọ́kàndínlógún (38,000)
4 Dáfídì sì wí pe, Níti èyí, ẹgbàáméjìlá (24,000) ni kí wọn jẹ́ alábojútó iṣẹ́ ilé fún Olúwa àti ẹgbàáta (6,000) ni kí ó ṣe olórí àti onídàájọ́.
5 Ẹgbàájì (4,000) ni kí ó jẹ́ olùtọ́jú ẹnu ọ̀nà àti ẹgbàajì (4,000) ni kí o sì jẹ́ ẹni ti yóò máa yin Olúwa pẹ̀lú ohun èlò orin, mo ti se èyí fún ìdí pàtàkì yìí.
6 Dáfídì sì pín àwọn ọmọ Léfì sí ẹgbẹgbẹ́ láàrin àwọn ọmọ Léfì Gérísónì, Kóhátì àti Mérárì.
7 Àwọn tí ó jẹ́ ọmọ Gérísónì:Ládánì àti Ṣíméhì.
8 Àwọn ọmọ LádánìJéhíélì ẹni àkọ́kọ́, Ṣétanì àti Jóẹ́lì ẹ̀kẹ́ta ní gbogbo wọn.