28 Iṣẹ́ àwọn ọmọ Léfì ni láti ran àwọn ọmọ Árónì lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ wọn fún ti ilé Olúwa: láti wà lábẹ́ ìkáwọ́ agbára ìlú, àti ẹ̀gbẹ́ ilé, àti ìwẹ̀nùmọ́ ti gbogbo ohun ìyàsọ́tọ̀ àti ṣíṣe ohun tìí ṣe iṣẹ́ ìsìn nínú ilé Olúwa.
29 Wọ́n sì wà ní ìkáwọ́ àkàrà tí wọ́n mú jáde láti orí tábìlì, àti ìyẹ̀fun fún ẹbọ ọrẹ, àti aláìwú pẹ̀tẹ̀, àti fún dídùn àti èyí tí a pòpọ̀, àti gbogbo onírúurú ìwọ̀n àti wíwọ̀n àti òṣùnwọ̀n.
30 Wọ́n sì gbọdọ̀ dúró ní gbogbo òwúrọ̀ láti dúpẹ́ àti láti yin Olúwa. Wọ́n sì gbọdọ̀ ṣe irú kan náà ní àsálẹ́.
31 Ní gbàkúgbà ẹbọ ọrẹ sísun ni wọ́n fi fún Olúwa ní ọjọ́ ìsinmi àti ní àsìkò oṣù tuntun àti ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì tí a paláṣẹ. Wọ́n gbọdọ̀ sìn níwájú Olúwa lójojúmọ́ ní iye tó yẹ àti ní ọ̀nà tí a ti paláṣẹ fún wọn.
32 Bẹ́ẹ̀ ni nígbà náà, àwọn ọmọ Léfì gbé ìgbékalẹ̀ jáde fún ìpàdé àgọ́, fún ibi mímọ́ àti, lábẹ́ àwọn arákùnrin àwọn ọmọ Árónì fún ìsìn ilé Olúwa.