15 Ẹ̀kẹtàdílógún sì ni Héṣírì,ekejìdílógún sì ni Háfísesì,
16 Ẹ̀kọkàndílógún sì ni Pétalà,ogún sì ni Jéhésékélì,
17 Ẹ̀kọ́kànlélógún sì ni Jákínì,ẹ̀kẹ́rìnlélogún sì ni Gámúlì,
18 Ẹ̀kẹtàlélógún sì ni Déláyà,ẹ̀kẹrìnlélógún sì ni Másíà.
19 Àwọn wọ̀nyí ni a yàn fún iṣẹ́ ìsìn nígbà tí wọ́n wọ ilé Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ìlànà àti àṣẹ tí a ti fi fún wọn láti ọwọ́ baba ńlá wọn Árónì gẹ́gẹ́ bí Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, tí pàṣẹ fun wọn.
20 Ìyòókù àwọn ọmọ Léfì:láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ámúríamù: Ṣúbáelì;láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ṣúbáélì; Jédeíà.
21 Àti gẹ́gẹ́ bí Réhábíà, láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Réhábíà:Íṣíà sì ni alákọ́kọ́.