20 Ìyòókù àwọn ọmọ Léfì:láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ámúríamù: Ṣúbáelì;láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ṣúbáélì; Jédeíà.
21 Àti gẹ́gẹ́ bí Réhábíà, láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Réhábíà:Íṣíà sì ni alákọ́kọ́.
22 Láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Iṣárì: Ṣélómótì;láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ṣélomótì: Jáhátì.
23 Àwọn ọmọ Hebúrónì: Jéríyà alákọ́kọ́, Ámáríyà elẹ́kẹjì, Jáhásélì ẹlẹ́kẹta àti Jékáméámù ẹlẹ́kẹrin.
24 Àwọn ọmọ Húsíélì: Mikà;nínú àwọn ọmọ Míkà: Ṣámírù.
25 Àwọn arákùnrin Míkà: Íṣíà;nínú àwọn ọmọ Íṣíà: Ṣekaríyà.
26 Àwọn ọmọ Mérarì: Málì àti Múṣì.Àwọn ọmọ Jásíà: Bẹ́nò.