25 Àwọn arákùnrin Míkà: Íṣíà;nínú àwọn ọmọ Íṣíà: Ṣekaríyà.
26 Àwọn ọmọ Mérarì: Málì àti Múṣì.Àwọn ọmọ Jásíà: Bẹ́nò.
27 Àwọn ọmọ Mérárì:Lati Jasíà: Bẹ́nò, Ṣóhámù, Ṣákúrì àti Íbírì.
28 Láti Málì: Élíásérì, ẹni tí kò ni àwọn ọmọ.
29 Láti Kíṣì: Àwọn ọmọ Kíṣì:Jérámélì.
30 Àti àwọn ọmọ Muṣì: Málì, Édérì àti Jérímotì.Èyí ni àwọn ọmọ Léfì, gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn.
31 Wọ́n sì ṣé kèké gẹ́gẹ́ bí àwọn arákùnrin wọn àwọn ọmọ Árónì ṣe ṣẹ́, níwáju ọba Dáfídì àti Ṣádókì, Áhímélékì, àti olórí ìdílé àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì. Àwọn ìdilé àgbààgbà arákùnrin wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀ lórí àwọn arakùnrin wọn kéékèèkéé.