1 Kíróníkà 27:1-7 BMY

1 Wọ̀nyí ni ìwé àkójọ orúkọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn olórí àwọn ìdílé, àwọn balógun ẹgbẹgbẹ̀rún àti àwọn balógun ọrọrún àti àwọn ìjòyè wọn. Tí ó n sin ọba nínú gbogbo ohun tí ó kan ìpín àwọn ọmọ ogun tí ó wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn ní oṣoṣù ní gbogbo ọdún. Ìpín kọ̀ọ̀kan jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ólé ẹgbàá mẹ́rin (24,000) ọkùnrin.

2 Ní ti alákòóso lórí ìpín kìn-ín-ni fún oṣù kìn-ín-ní jẹ́ Jáṣóbéámù ọmọ Ṣábídiélì àwọn ọkùnrin ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ólé ẹgbàá mẹ́rin ní ó wà ní abẹ́ (24,000) ìpín tirẹ̀.

3 Ó jẹ́ ìran ọmọ pérésì àti olóyè fún gbogbo àwọn ìjòyè ológun fún oṣù kìn-ín-ní.

4 Alákòóso fún ìpín àwọn ọmọ-ogun fún oṣù kejì jẹ́ Dódáì ará Áhóhì; Míkílótì jẹ́ olórí ìpín tirẹ̀. Ọkùnrin ẹgbàá ni ó wà ní ìpín tirẹ̀. (24,000).

5 Olórí àwọn ọmọ ogun ẹlẹ́ẹ̀kẹta fún oṣù kẹta jẹ́ Bénáyà ọmọ Jéhóíádà àlùfáà. Ó jẹ́ olóyè, àwọn ọkùnrin ẹgbàá méjìlá ní ó wà ní ìpín tirẹ̀. (24,000).

6 Èyí ni Bénáyà náà tí ó jẹ́ ọkùnrin ńlá láàrin àwọn ọgbọ̀n àti lórí àwọn ọgbọ̀n. Ọmọ Rẹ̀ Ámíṣábádì jẹ́ alákóso lórí ìpín tirẹ̀.

7 Ẹlẹ́ẹ̀kẹrin fún oṣù kẹrin, jẹ́ Ásáhélì arákùnrin Jóábù: ọmọ Rẹ̀ Ṣébádáyà jẹ́ arọ́pò Rẹ̀. Ẹgbàá méjìlá ọkùnrin (24,000) ni ó wà ní ìpín Rẹ̀.