14 Ìkọkànlá fún oṣù kọkànlá jẹ́ Bénáyà ará pírátónì ará Éfíráímù ọkùnrin ẹgbàá méjìlá (24,000) ni ó wà ní ìpín tirẹ̀.
15 Ìkejìlá fún oṣù kejìlá jẹ́ Hélídáì ará Nétófátì láti ìdílé Ótíníélì. Ẹgbàá méjìlá ọkùnrin (24,000) ni ó wà ní ìpín tirẹ̀.
16 Àwọn ìjòyè lórí àwọn ẹ̀yà tí Ísírẹ́lì:lórí àwọn ará Réúbẹ́nì: Éliésérì ọmọ Ṣíkírì;lórí àwọn ará Ṣíméónì: Ṣéfátíyà ọmọ Mákà;
17 lórí Léfì: Háṣábíà ọmọ Kémúélì;lori Árónì: Ṣádókù;
18 lórí Júdà: Élíhù arákùnrin Dáfídì;lóri Ísákárì: Ómírì ọmọ Míkáélì;
19 lórí Ṣébúlúnì: Íṣímáíà ọmọ Óbádáyà;lori Náfitalì: Jérímótì ọmọ Áṣíríélì;
20 lórí àwọn ará Éfíráímù: Hòṣéà ọmọ Áṣásíà;lorí ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè: Jóélì ọmọ Pedáyà;