15 Àwọn ọmọ Jósíà:Àkọ́bí ọmọ Rẹ̀ ni Jóhánánì,èkejì ọmọ Rẹ̀ ni Jéhóíákímù,ẹ̀kẹta ọmọ Rẹ̀ ni Ṣédékíà,ẹ̀kẹ́rin ọmọ Rẹ̀ ni Ṣálúmù.
16 Àwọn ìran ọmọ Jéhóíákímù:Jékóníà ọmọ Rẹ̀,àti Ṣedékíà.
17 Àwọn ọmọ Jéhóíákímù tí a mú ní ìgbékùn:Ṣálátíélì ọmọ Rẹ̀ ọkùnrin,
18 Málíkírámù, Pédáíyà, Ṣénásárì, Jékámíà, Hósámà àti Nédábíà.
19 Àwọn ọmọ Pédáíyà:Ṣérúbábélì àti Ṣíméhì.Àwọn ọmọ Ṣérúbábélì:Mésúlámù àti Hánáníyà,Ṣélómítì ni arábìnrin wọn.
20 Àwọn márùnún mìíràn sì tún wà:Hásúbà, Óhéhì, Bérékíà, Hasádíà àti Jusabi-Hésédì.
21 Àwọn ọmọ Hánáníyà:Pélátíà àti Jeṣáíà, àti àwọn ọmọ Réfáíà, ti Árínánì, ti Ọbadíà àti ti ṣékáníà.