12 Ésítónì sì jẹ́ baba Bétí-ráfà, Páséà àti Téhína ti baba ìlú Náhásì. Àwọn wọ̀nyí ni ọkùnrin Rékà.
13 Àwọn ọmọ Kénásì:Otíníẹ́lì àti Ṣéráíà.Àwọn ọmọ Ótiníẹ́lì:Hátatì àti Méónótaì.
14 Méónótaì sì ni baba Ófírà.Ṣéráíà sì jẹ́ baba Jóábù,baba Géhárásínù. A pè báyìí nítorí àwọn ènìyàn àwọn onísọ́nà niwọ́n.
15 Àwọn ọmọ kálébù ọmọ Jéfúnè:Irú, Élà, àti Námù.Àwọn ọmọ Élà:Kénásì.
16 Àwọn ọmọ Jéhálélélì:Ṣífù, ṣífà, Tíríà àti Ásárélì.
17 Àwọn ọmọ Ésírà:Jétẹ́rì, Mérédì, Éférì àti Jálónì. Ọ̀kan lára àwọn aya Mérédì sì bí Míríámù, ṣámáì àti Íṣíbà baba Éṣítémóà.
18 Aya Rẹ̀ Jéhúdijà sì bí Jérédì baba Gédórì, Hébérì baba sókè àti Jékútíẹ́lì bàbá Sánóà. Àwọn wọ̀nyí ni ọmọbìnrin ọmọ Bítíà ẹni ti Mérédì ti fẹ́.