4 Pénúélì sì ni baba Gédórì, àti Édérì baba Húṣà.Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Húrì, Àkọ́bí Éfúrátà àti baba Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.
5 Áṣárì bàbá Jékóà sì ní aya méjì, Hélà àti Nárà.
6 Nárà sì bí Áhúsámù, Héférì Téménì àti Háhásítarì. Àwọn wọ̀nyí sì ni àwọn ọmọ Nátà.
7 Àwọn ọmọ Hélà:Ṣérétì Ṣóárì, Étanì,
8 Àti kósì ẹnítí ó jẹ́ baba Ánúbì àti Hásóbébà àti ti àwọn Ẹ̀yà Áháríhélì ọmọ Hárúmù.
9 Jábésì sì ní olá ju àwọn ẹ̀gbọ́n Rẹ̀ ọkùnrin lọ. Ìyá Rẹ̀ sì sọ ọ́ ní Jábésì wí pé, “Mo bí i nínú ìpọ́njú.”
10 Jábésì sì kígbe sókè sí Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí pé, “Áà, Ìwọ yóò bùkún fún, ìwọ yóò sì mú agbégbé mi tóbi! Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ kí ó wà pẹ̀lú mi kí o sì pa mí mọ́ kúrò nínú ibi; kí èmi kí ó le ní ìdáǹdè kúrò nínú ìrora.” Ọlọ́run sì gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ Rẹ̀