1 Ǹjẹ́ àwọn ọmọ Rúbẹ́nì, àkọ́bí Ísírẹ́lì. (Nítorí òun ni àkọ́bí; ṣùgbọ́n, bí ó ti ṣe pé ó ba ẹní baba Rẹ̀ jẹ́, a fi ogún ìbí Rẹ̀ fún àwọn ọmọ Jóṣẹ́fù ọmọ Ísírẹ́lì: a kì yóò sì ka ìtàn ìdílé náà gẹ́gẹ́ bí ipò ìbí.
2 Nítorí Júdà borí àwọn arákùnrin Rẹ̀, àti lọ́dọ̀ Rẹ̀ ni alásẹ ti ń jáde wá; ṣùgbọ́n ogún ìbí jẹ́ ti Jóṣẹ́fù),
3 àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àkọ́bí Ísírẹ́lì ni:Hánókù àti Pálù, Hésirónì àti Kárímì.
4 Àwọn ọmọ Jóẹ́lì:Ṣémáíà ọmọ Rẹ̀, Gógù ọmọ Rẹ̀,Ṣíméhì ọmọ Rẹ̀.
5 Míkà ọmọ Rẹ̀,Réáíà ọmọ Rẹ̀, Báálì ọmọ Rẹ̀.
6 Béérà ọmọ Rẹ̀, tí Tígílátì-pílínésérì ọba Ásíríà kó ní ìgbékùn lọ: ìjòyè àwọn ọmọ Rúbẹ́nì ni òun jẹ́.
7 Àti àwọn arákùnrin Rẹ̀ nípa ìdílé wọn, nígbà tí a ń ka ìtàn ìdílé ìran wọn:Jélíélì àti Ṣékáríà ni olórí.