14 Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Ábíháílì, ọmọ Húrì, ọmọ Járóà, ọmọ Gílíádì, ọmọ Míkàẹ́lì, ọmọ Jésíháì, ọmọ Jádò ọmọ Búsì.
15 Áhì, ọmọ Ábídélì, ọmọ Gúnì, olórí ilé àwọn baba wọn.
16 Wọ́n sì ń gbé Gílíádì ní Básánì àti nínú àwọn ìlú Rẹ̀, àti nínú gbogbo ìgbéríko Sárónì, ní agbégbé wọn.
17 Gbogbo wọ̀nyí ni a kà nípa ìtàn-ìdílé, ní ọjọ́ Jótamù ọba Júdà, àti ní ọjọ́ Jéróbóámù ọba Ísírẹ́lì.
18 Àwọn ọmọ Rúbẹ́nì, àti àwọn ọmọ Gádì, àti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè, nínú àwọn ọkùnrin alágbára tí wọ́n ń gbé aṣà àti idà, tí wọ́n sì ń fi ọrun tafà, tí wọ́n sì mòye ogun, jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ènìyàn o le ẹgbẹ̀rinlélógún dín ogójì, tí ó jáde lọ sí ogún náà.
19 Wọ́n sì bá àwọn ọmọ Hágárì jagun, pẹ̀lú Jétúrì, àti Néfísì àti Nádábù.
20 Nígbà tí wọ́n sì rí ìrànlọ́wọ́ gbà si, a sì fi àwọn ọmọ Hágárì lé wọn lọ́wọ́, àti gbogbo àwọn tí ó wà pẹ̀lú wọn; nítorí ti wọn képe Ọlọ́run ní ogun náà, òun sì gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn; nítorí tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ wọn lé e.